Àwọn dókítà ti sọ fún mi pé kí n dẹ́kun sígà fífà àti ọtí mímu-Tope Osoba. Nibo Laye Koju Si?

Àwọn dókítà ti sọ fún mi pé kí n dẹ́kun sígà fífà àti ọtí mímu-Tope Osoba. Nibo Laye Koju Si?
Published

Tope Osoba ni gabjugbaja oṣerebinrin ti aye n pariwo iku rẹ lọwọlọwọ lori ayelujara.

Oriṣiirisi awuyewuye si ni iku rẹ ti mu dani bayii.

Ọdun to kọja ni Oloogbe Tope Osoba ṣabẹwo si BBC News Yoruba, nibi to ti ṣalaye nipa awọn alakọja rẹ lori aisan jẹjẹrẹ ọmu to kọlu u lojiji.

Bo ṣe gba awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lamọran, naa lo tun rọ gbogbo awọn obinrin kaakiri lati maa ṣayẹwo ara wọn loore-koore.

O ṣalaye lori ipa i oluṣọ rẹ ko lasiko naa pẹlu igbagbọ rẹ ninu abal fọnran fidio yii.

Bakan naa lo tun fidi rẹ mulẹ pe aisan jẹjẹrẹ kii ṣe idajọ iku fun eeyan, nitori pe bi eeyan ba ti ni igbagbọ, to si gba itọju to pe ye, aisan naa yoo poora kuro lara.

Foluke Daramola ṣalaye pe ko ki n ṣe aisan jẹjẹrẹ ọyan lo pa Tope Osoba.

O ni pe:- "Lẹyin oṣu meji si mẹta to gba itọju tan, emi ati ẹ tun pada lọ sileewosan, dokita si fidi ẹ mulẹ fun wa pe ko si jẹjẹrẹ yẹn mọ.

"Koda, ọyan rẹ ti wọn ge, wọn o ge gbogbo ẹ, wọn kan yọ koko yẹn ni nibẹ ni, ko dẹ ti i di jẹjẹrẹ.

"Awọn nnkan mi-in wa nidii rẹ ti awọn ọlọpaa n ṣe iwadii le lori, ti ko ti i ye awa gan-an, ko ti i da wa loju pato, amọ ki i ṣe jẹjẹrẹ lo pa a."

Nipa awọn onitiata ti ko pọ nibi eto naa, Daramola sọ pe ki i ṣe pe wọn ko nifẹẹ Oloogbe, o ni kaluku lo ni tiẹ lara to n ran labẹ aṣọ.