"Ó ṣe ni láàánú pé gómìnà tó fi ebi pa aráàlú, tí kò ṣe dáadáa, ni wọ́n tún fi màgòmágó dá padà síjọba"

"Ó ṣe ni láàánú pé gómìnà tó fi ebi pa aráàlú, tí kò ṣe dáadáa, ni wọ́n tún fi màgòmágó dá padà síjọba"
Published

Eto idibo gomina ni ipinlẹ Ekiti ti waye lọjọ Satide, ogunjọ osu kẹwa, o si ti kasẹ nilẹ.

Koda, ajọ eleto idibo, INEC, ti kede gomina to wa lori aleefa, Abiodun Oyebamiji pe oun lo wọle fun saa keji.

Amọ ọ̀rọ̀ ko tii tan nipa eto idibo naa tori awọn oludije latinu ẹgbẹ oselu alatako to kopa ninu ibo naa ti n fapa janu.

Lara awọn oludije gomina nipinlẹ Ekiti to ba ikọ iroyin BBC News Yoruba sọrọ ni gomina to wọle fun saa keji, Abiodun Oyebamiji.

Bakan naa, awọn oludije gomina latinu ẹgbẹ oselu alatako bii ADC ati Accord sọ ero wọn nipa esi ibo naa.

Nnkan tawọn oludibo se lasiko ibo ko sẹlẹ ri nipinlẹ Ekiti, ki wọn dibo yan gomina kan fun saa keji, ko waye ri - Oyebamiji

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, gomina ti wọn tun dibo yan pada fun igba keji nipinlẹ Ekiti, Abiodun Oyebamiji dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn eeyan ipinlẹ naa, fun bi wọn se fun oun laaye lati sin wn fun igba keji.

"Nnkan tawọn oludibo se lasiko ibo ko sẹlẹri nipinlẹ Ekiti, ki wọn dibo yan gomina kan fun saa keji, ko waye ri.

Mo si n fi da wọn loju pe maa sin wọn pẹlu ibẹru Ọlọrun, pẹlu otitọ ati gbogbo agbara ti Ọlọrun fun wa.

A ko ni ja wọn ni tanmọ, gbogbo erongba wọn patapata nipa pe ki ilu lọ siwaju, ki aabo wa nipinlẹ Ekiti, la maa se."

"Ẹyin naa ri pe ibo ti di tita bayii ni ọja, lootọ ni gomina pe mi pe oun n bọ wa ri mi, mo si ni n ko setan lati wa ri bayii"

Bakan naa, oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oselu ADC, Dare Bejide, lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ sọ ero rẹ nipa abajade esi ibo naa.

"Ọrọ ibo ni pe ti ijọba kan ba wa nipo, ti ko ba se daadaa, a dibo le wọn kuro nibẹ, ka si fi ibo gbe ijọba tuntun wọle.

Sugbọn ẹyin naa ri pe ibo ti di tita bayii ni ọja, lootọ ni gomina pe mi ni wakati meji sẹyin, o dẹ ni oun n bọ wa ri mi, mo si ni n ko setan lati wa ri bayii.

O se ni laanu pe gomina to fi ebi pa ara ilu, ti gbogbo wa mọ pe ko se daadaa, ni wọn tun fi magomago da pada sori ijọba."

"137,000 awọn agbofinro lo wa si ipinlẹ Ekiti lasiko idibo, tori kinni, wọn dẹ gbe 'Bullion Van' wọle"

David Opeyemi Falegan, tii se oludije gomina fẹgbẹ oselu Accord nipinlẹ Ekiti naaba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ lori ero rẹ nipa abajade esi ibo gomina to kọja.

" O ti ni loju pe ko si eto idibo to waye nipinlẹ Ekiti.

Ileẹjọ lo maa ba wa da ẹjọ naa, tori lawọn agọ idibo kan, ko si ẹgbẹ oselu Accord lara awọn iwe idibo.

Se o yẹ ko ri bẹẹ, awọn ọmọ to fẹ dibo fun wa, wọn n dunkooko mọ wọn, wọn tun n fi owo ra ibo, se o yẹ ko ri bẹẹ.

137,000 awọn agbofinro lo wa si ipinlẹ Ekiti lasiko idibo, tori kinni, wọn dẹ gbe ‘Bullion Van’ wọle, tawọn eeyan n wo wa lori ayelujara.

Awọn agbofinro to wa si Ekiti, to ba se awọn ọmọ wa ti wọn ji gbe ni agbegbe Ẹda Oniyo ati nipinlẹ Oyo ni wọn lọ gba idande wọn ni, ko ba dara.

Eto idibo ipinlẹ Ekiti lo jẹ wọn logun, eyi si ti ni loju, a ko se idibo kankan nipinlẹ Ekiti, a si maa lọ sile ẹjọ."