You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn agbébọn ṣèkọlù sáwọn àgbẹ̀ nínú oko, pa mẹ́sàn-án, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ
Ko din ni awọn agbẹ mẹsan-an ti ọpọ araalu si di awati ni ilu Birnin-Gwari, ipinlẹ Kaduna nigba ti awon agbebon ṣekọlu si wọn.
Ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Abamẹta ni iroyin sọ pe iṣẹlẹ naa waye lasiko tawọn agbẹ naa n ṣiṣẹ ninu oko wọn.
Gẹgẹ bi awọn araalu ti ikọlu naa ṣoju wọn ṣe sọ, ikọlu naa waye nigba ti awọn agbebon meji kan fẹ gbiyanju lati ja ọkada agbẹ kan gba.
O ni eyi fa ifanfa laaarin awọn agbẹ naa atawọn agbebọn naa eyi to ṣokunfa iku ọkan lara awọn agbebọn naa.
Araalu naa ni agbebọn keji ti ko padanu ẹmi rẹ lọ pe awọn yooku rẹ wa ti wọn si bẹrẹ si ni ṣọṣẹ sawon agbẹ to n ṣiṣẹ ni agbegbe naa.
Wọn ni oku eeyan mẹsan-an ni wọn sawari ni ori papa ti ikọlu naa ti waye.
Bi o tilẹ jẹ pe wọn ko i tii mọ mẹta ninu awọn eeyan to padanu ẹmi wọn naa, awọn araalu fi orukọ awọn mẹfa lede.
Orukọ awọn eeyan naa ni wọn pe ni Habibu Danko, Zaharaddin Musa Gumu, Maibaka Mayana, Umar Maibaka, Yusufu Dankatakaki ati Shaf'iu Kagadama.
"Awọn fijilante ko le wọnu igbo lati lọ wa awọn ti wọn ji gbe nitori ibẹ lagbara pupọ"
Awọn agbebọn naa tun ji ọpọ awọn agbẹ naa gbe lọ, tawọn araalu si n bẹru pe kawọn agbebọn naa ma pa awọn eeyan ọhun.
O ni ọpọ awọn fijilante to wa ninu ilu ni wọn ko le lọ sinu igbo lati lọ wa awọn eeyan naa nitori ibẹ lagbara lati wọ.
Araalu mii to tun ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe wiwa awọn eeyan atawọn oku mii ṣi n tẹsiwaju lati fidi iye eeyan to padanu ẹmi wọn n inu ikọlu naa mulẹ.
Awọn araalu sọ pe ikọlu yii lo n waye lẹyin ti ikọlu to kọkọ waye lọjọ Ẹti nibi ti awọn agbebọn ṣekupa ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ya'u gayam ni opopona Birnin-Gwari si Kaduna, ti wọn si tun ji ọkada rẹ gbe.
Wọn kọminu pe ikọlu naa ti n waye leralera, tawọn eeyan ko le lọ si oko wọn mọ lai si ibẹru ikọlu awọn agbebọn.
Ẹ o ranti pe ni ọjọ Kẹtalelogun, oṣu Kẹfa ni awọn agbebọn yawọ agbegbe Kuyello ni Birnin Gwari kan naa, ti wọn si pa agbẹ mẹsan-an.
Agbegbe Birnin-Gwari jẹ ọkan lara ibi ti ikọlu awọn agbebọn ti n waye leralera ni ipinlẹ Kaduna bawọn agbeṣumọmi ṣe ti gba gbogbo igbo to wa ni agbegbe naa kan.