You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin kan kú lẹ́yìn Eégún n‘Ibadan, Atọ́kùn eégún, Asòlẹ̀kẹ̀, kó sí gbaga ọlọ́páá báwọn ọmọ ẹ̀yìn eégún ṣe sálọ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi ọwọ ofin mu eegun Asoleke niluu Ibadan, lori iku ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) kan ti wọn ni wọn ṣa pa.
Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olayinka Ayanlade, fi sita lọjọ Aje, ọjọ kẹfa oṣu Keje ọdun 2026 yii, fidi ẹ mulẹ pe ọwọ ti ba eegun naa lori iku Oloogbe Sefiu Kehinde.
Ọlọpaa sọ pe ikọlu ti eegun naa atawọn ọmọ ẹyin rẹ si si Sefiu lo pa a lọjọ Aiku, ọjọ karun-un oṣu Keje ọdun 2026.
Eegun Asoleke atawọn to tẹle e (mọ ti won ti salọ bayii), kọlu Sefiu Kehinde pẹlu awọn nnkan ija oloro oriṣiiriṣii - Ọlọpaa
Atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Oyo fi lede, ṣalaye pe agbegbe Labiran, niluu Ibadan ni iṣẹlẹ yii ti waye.
Ayanlade ṣalaye pe eegun Asoleke atawọn to tẹle e (mọ ti won ti salọ bayii), kọlu Sefiu Kehinde pẹlu awọn nnkan ija oloro oriṣiiriṣii.
O ni eyi naa lo si pada fa iku oloogbe naa.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi:
"Ẹka agọ ọlọpaa Mapo ni wọn fi iṣẹlẹ yii to leti lọjọ karun-un oṣu Keje ọdun 2026, obinrin kan; Abilekọ Aderemi lo mu ẹsun naa wa.
"O ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa loun gba ipe kan latọdọ ẹgbọn oun obinrin, to ni eegun Asoleke atawọn ọmọ ẹyin rẹ kọlu aburo awọn ọkunrin, Sefiu Kehinde lasiko ti wọn n kọja lọ lagbegbe Labiran, niluu Ibadan."
Awọn nnkan ọsẹ́ bii aake ati ada lo ni awọn eeyan naa fi ba Oloogbe Sefiu ja, wọn ṣa a, wọn si da oju ọgbẹ si i lara bi olufisun naa ṣe sọ.
"Ọwọ ofin ti ba eegun Asoleke, awọn mẹrin ti wọn pe ni ọmọ ẹyin rẹ si ti sa lọ"
Atẹjade ọlọpaa sọ pe kia ni ikọ agbofinro ti de Labiran, wọn gbe Sefiu to wa ninu ẹjẹ lọ sile iwosan fun itọju kia, amọ dokita sọ fun wọn pe o ti ku bi wọn ṣe n gbe e debẹ.
"Bi ọrọ naa ṣe n lọ lọwọ, ọwọ ofin ti ba eegun Asoleke, awọn mẹrin ti wọn pe ni ọmọ ẹyin rẹ si ti sa lọ."
Wọn fi kun un pe awọn ẹbi Oloogbe Sefiu beere pe ki wọn yọnda oku rẹ fawọn lati sin nilana ẹsin Islam, eyi ti ọlọpaa fi aaye rẹ silẹ fun wọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo, CP Abimbola Ayodeji Olugbemiga,ti ni ki wọn taari ẹsun naa si ẹka to n ri si iwadii iwa ọdaran (SCID), fun itẹsiwaju.
Wọn fi da araalu loju pe iṣẹ n lọ lati mu awọn to sa lọ naa, bẹẹ ni wọn rọ araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba nipa fifi ohun to ba n ṣẹlẹ to ọlọpaa leti kia.
Olubadan ti kilọ ṣaaju fawọn eegun lati ṣe pẹlẹ
Saaju ki iṣẹlẹ yii too waye ni Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Ladoja, ti kilọ fun awọn eegun atawọn ọmọ ẹyin wọn lati ṣe pẹlẹ lasiko ọdun wọn.
Olubadan Ladoja rọ wọn lati ma ṣe lọwọ ninu jagidijagan tabi iwa ti yoo lodi sofin kankan.
Ninu atẹjade ti Olubadan fi kilọ naa lo ti ni dandan kọ ni ki ọdun eegun mu jagidijagan tabi iwa ọdaran dani.
Ọba Ladoja sọ pe ọdun eegun ko si fun ipari ija ọlọdun gbọọrọ, ija agba tabi ẹsan gbigba laaarin eegun alatako.
Kabiyesi Olubadan kilọ ninu atẹjade naa ti Akọwe iroyin rẹ; Adeola Oloko, fi sita, pe eegun to ba lukun ofin yoo jiya ofin.
Amọ pẹlu ikilọ naa, eegun Asoleke di ero gbaga.
Ọdọọdun ni ọdun eegun maa n waye n'Ibadan
Fun ọdun gbọọrọ ni wọn ti n ṣe ayẹyẹ ọdun eegun niluu Ibadan, ọdọọdun ni ayẹyẹ naa si maa n waye.
Ninu ọdun eegun ilu Ibadan ni ọpọ ọmọ ilu naa ti maa n ṣafihan aṣa ati iṣẹ ilu nla yii, ti wọn si maa n sọ awọn itan to rọ mọ ilu naa.
Ọdun eegun ilu Ibadan wa fun idanimọ, ipese fawọn alalẹ, awẹjẹ wẹmu, ijo jijo, ipẹjọ awọn eeyan agbegbe ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọlọkan-o-jọkan eegun lo maa n jade nibi ayẹyẹ ọdun eegun naa, kaluku yoo pitu ọwọ rẹ pẹlu awọn ero lẹyin, awọn mi-in si ni eewọ ti awọn eeyan gbọdọ bọwọ fun ninu wọn.