Àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ń lo ẹ̀rọ drone àti crypto láti mú ìmúgbòòrò bá iṣẹ́ ibi wọn - Ajọ UN kìlọ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ iṣọkan agbaye, UN ti ṣe ikilọ nla fun awọn alakoso ilẹ Naijiria, Iwọ-Oorun Afrika ati Sahel lati maa ṣọra fun ikọ awọn agbesunmọmi to n lo ẹrọ duroonu ati owo ori ayelujara ti a mọ si crypto, eyi ti wọn fi n tọpinpin lati mu imugbooro ba iṣẹ buruku wọn.

UN sọ pe ẹkun Iwọ-Oorun ilẹ Naijiria, to fi mọ ẹkun Iwọ-Oorun ilẹ Afrika ati ẹkun Sahel ni awọn agbesunmọmi yii ti n lo awọn ohun elo igbalode naa, lojuna lati ma jẹ ki ẹnikẹni le bori wọn.

Akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, Leonardo Simão, lo ke gbajare naa fun awọn adari ilẹ Afrika, Sahel ati awọn alabojuto ileeṣẹ un to wa lẹkun Iwọ-Oorun Afrika ati Sahel nibi ipade igbimọ ajọ iṣọkan agbaye lori eto aabo.

Leonardo Simão sọ pe gbogbo ọna ni awọn agbesunmọmi naa n wa lati rii daju pe ko si ikọ ologun tabi eleto aabo to le kapa wọn lagbaye, paapaa nilẹ Afrika.

Nibi ipade ọhun ni Simão ti ṣe atupalẹ iroyin idagbasoke to waye lẹkun Iwọ-Oorun ilẹ Afrika laaarin ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 si ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2026.

Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi ìpàdé ọ̀hún?

Igbimọ naa ṣagbeyẹwo oniruuru ohun to nii ṣe pẹlu ọrọ oṣelu, eto aabo ati igbe aye awọn eeyan kaakiri awọn ẹkun wọnyi.

Ipade yii lo waye lẹyin ti ajọ naa ṣe ipinnu lati fi kun ọjọ agbekalẹ UNOWAS siwaju di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2029.

Gẹgẹ bi Simão ṣe sọ siwaju, o ni awọn agbesunmọmi naa n ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe awọn lo imọ ẹrọ igbalode lati maa fi ṣiṣẹ ibi kaakiri orileede to sunmọ ara wọn.

"Awọn ẹgbẹ agbesunmọmi ti n ṣe afikun nipa lilo ẹrọ igbalode duroonu, awọn ẹrọ ikansira-ẹni ti igbalode ati owo ori ayelujara ti igbalode (cryptocurrencies), bi wọn ṣe n ṣe iṣakoso nipa iṣọkan iṣẹ wọn kaakiri aale awọn orileede," Simão sọ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe iṣẹ awọn ẹgbẹ buruku wọnyi ti wa jinlẹ debi wi pe niṣe ni wọn fi ṣe okoowo laaarin ara wọn, leyi to n jẹ ki wọn maa gba iṣakoso awọn agbegbe ati eto ọrọ ajẹ, ti wọn si n jẹ ki awọn araalu maa sọ ireti nu ninu awọn ijọba.

Simão sọ pe: "iṣoro naa le gidi, paapaa lẹkun Sahel ati Ariwa Naijiria. Awọn iṣẹ wọn ni asopọ to kọja aala orileede, wọn si jẹ ọna lati mu iṣakoso ilẹ ati ọrọ aje wọn lagbara. Eyi si n ba igbẹkẹle awọn eeyan niu aṣẹ ijọba orileede jẹ, pẹlu ipalara to buru si iṣọkan awujọ."

Ajọ iṣọkan agbaye wa tọka Naijiria, Niger ati Burkina Faso gẹgẹ bi awọn orileede ti wọn n fi gbogbo igba koju oniruuru ikọlu awọn agbesunmọmi, ijinigbe ati iku ati ifarapa to po laaarin awọn araalu.

O ni bi eto aabo ṣe n buru sii, awọn eeyan to din diẹ ni miliọnu meje (6.8m) ni wọn ti di alainilelori, nigba ti awọn mejidinlọgba-le-ni-miliọnu kan (1.28m) kaakiri ẹkun wọnyi ti wa ni ipo atipo.

Simão ni awọn obinrin ati awọn ọmọde ni wọn fi ara kaaṣa julọ ninu ikọlu naa, ati pe eto aabo to mẹhẹ ati aisi owo to to ti da awọn eeyan lọwọ kọ lati ni anfaani si awọn agbegbe to wa ninu ailera.

Bo tilẹ jẹ pe ipo eto aabo ti n bọ si ipo to le koko, o gba pe ifọwọsowọpọ awọn ẹkun ti n lọ lọwọ, to fi mọ ṣiṣi ẹnubode aala Kamba to wa laaarin orileede Naijiria ati Niger.