You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀lẹ́bí St. Janet kéde bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ
Awọn mọlẹbi olorin Highlife to di oloogbe, Janet Oluwatoyosi Ajilore ti awọn eeyan tun mọ si Mama Yabis ti kede bi eto isinkun rẹ yoo ṣe lọ.
Ọsẹ to kọja ni olorin naa ti inangijẹ rẹ n jẹ 'St. Janet' jade laye lẹyin aisan kan gẹgẹ bii a sẹ gbọ.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni ilu-mọ-ọn-ka olorin naa fi aye silẹ, gẹgẹ bi awọn to sunmọ ọn ṣe gbe e sita.
Bi eto isinku St Janet yoo ṣe lọ
Gẹgẹ bii ikede to jade lati akata awọn mọlẹbi rẹ, ọjọ Iṣẹgun, to jẹ ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni wọn yoo ṣe isin aṣale onigbagbọ fun ni aago mẹrin irọlẹ.
Ọjọ naa tun ni awọn olorin akẹgbẹ rẹ yoo kọwọrin pẹlu abẹla lọwọ wọn ni iranti rẹ.
Eyii yoo waye ninu ọgba ileeṣẹ iroyin AIT/Faaji FM to wa ni Kola Alagbado.
To ba di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹjọ ni eto isinku yoo waye nile rẹ to wa ni ojule 73, Asipa, Ijeja, oke Odo Shoyoye, niluu Abeokuta, ipinlẹ Ogun ni aago mẹwaa aarọ.
Ọdun 1973 ni wọn bi St Janet ko to dagbere faye ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii.
Wọnyi lawọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa St. Janet
Ọmọ ilu Ile Ife, nipinlẹ Osun ni Oloogbe naa.
Ile ẹkọ girama Ooni Girl's High School, niluu Ile-Ife ni Oloogbe St.Janet lọ, o si tun kawe ni fasiti ilu Eko ti a mọ si Lagos State University (LASU).
Ko too di olorin aye to n kọ Juju ati orin aṣa papọ, akọrin ni oloogbe naa ninu ijọ C/S.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo maa n gbadun orin ibalopọ to maa n kọ lai da ọrọ kankan pe, eyii to mu okiki rẹ kan.
Nibi orin aṣa naa ni wọn ti fun St. Janet ni inagijẹ Mama Yabis.
St. Janet funra rẹ a maa pe ara rẹ ni General Overseer, iyẹn adari ijọ Saint Bottles Cathedral.