Àlàyé rèé lórí ìdí tí báálé ilé ṣe ju ọmọ rẹ̀ méjì sílẹ̀ láti orí ilé alájà mẹ́ta, tó tún fẹ́ ju ìyá wọn náà tẹ̀le

Oríṣun àwòrán, Magic FM Aba
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Abia ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin kan to ju awọn ọmọ rẹ meji silẹ lati ori ile alaja mẹta to si tun fẹẹ ju iyawo rẹ naa silẹ.
Agbegbe ti wọn n pe ni Umuobe to wa nitosi ikorita baraaki to wa loju ọna Opobo, iyẹn lagbegbe Obingwa, Aba, ipinlẹ Abia.
Ọgbọn ọjọ oṣu Keje, ọdun 2026 la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye, koda wọn ni ọkunrin naa tun ni erongba lati gba ẹmi ara rẹ nipa fifo jabọ lati ori aja ọhun, ko to di pe ọwọ tẹ ẹ.

Oríṣun àwòrán, Magic FM Aba
"Ibi ti ọkunrin naa ti n pokaka iku ni awọn ọlọpaa ti ba a niwaju ile rẹ, lẹyin to ti fi ori gbalẹ lasiko wahala naa"
Ọpọ awọn to ri ohun to ṣẹlẹ yii ni wọn sare lọ sibẹ lati mọ ohun to ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn fi ọkunrin yii to n faraya.
Lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ibi ti ọkunrin naa ti n pokaka iku ni wọn ti ba a niwaju ile rẹ, lẹyin to ti fi ori gbalẹ lasiko wahala naa.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ọkunrin naa pinnu lati gbẹmi ara rẹ ni, bẹẹ lawọn kan n sọ pe asiko to fẹ ju iyawo rẹ lo ṣeeṣi jabọ.
Wọn ni ọkunrin naa ti ju awọn ọmọ rẹ lati ori ile alaja naa silẹ.
Awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn wa nibẹ la gbọ pe wọn sare gbe awọn ọmọ naa lọ sile iwosan fun itọju.
Titi di asiko ti a pari akọjọpọ iroyin yii la ko tii gbọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ti gbe ọkunrin naa lọ.





























