You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọ́pàá gbé Baba Adeniyi Adeyemi tíjọba fẹ̀sùn ìdásílẹ̀ ayédèrú iléeṣẹ́ àti àjẹbánu kàn, Gbajabiamila ní òun yóò pe Afurasí náà lẹ́jọ́ N10bn fẹ́sùn ìbanilórúkọ jẹ́
Ọrọ ba ibomi-in yọ fun Ọmọọba Adeniyi Adeyemi, ẹni ti ijọba apapọ Naijiria n fẹsun idasilẹ ayederu ileeṣẹ ati ajebanu kan, pẹlu bi wọn ṣe tun lọ fi ọlọpaa gbe baba rẹ niluu Ogbomoso, lọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Keje ọdun 2026 yii.
Ẹ o ranti pe owo to to N1.3bn ni wọn ni igbimọ Presidential Foreign Intervention Promotion Council ni lati ṣalaye, eyi ti Ọmọọba Adeyemi sọ pe oun ni ọga agba ibẹ.
Adeyemi lo ni oun gbe ileeṣẹ naa kalẹ nilana to gba ọfiisi aarẹ kọja, amọ ti ijọba Naijiria ni awọn ko mọ nipa rẹ.
Ọrọ naa ti de ile ẹjọ giga ilu Abuja, awọn ẹsun bi igbimọpọ huwa to lodi sofin, iwe yiyi ati pipe ara ẹni ni oun ti a ko jẹ ni ijọba apapọ si fi n kan Adeyemi, ti Femi Gbajabiamiala atawọn mẹwaa kan si jẹ ẹlẹrii ijọba ninu ẹjọ naa.
Alaye ree lori bi wọn ṣe mu Baba Adeyemi ati alejo to wa ki i
Nipa bo ṣe di pe ọlọpaa wọle mu Baba Adeyemi laaarọ ọjọ Aje naa, o ṣoju mi koro kan ṣalaye pe:
"Mọto mẹrin ni awọn ọlọpaa gbe wa, wọn wọle awọn obi Ọmọọba Adeyemi Adeniyi to wa lagbegbe Road Safety, niluu Ogbomoso, wọn si gbe baba rẹ ati alejo to wa ki i lọ.
Ẹni naa to jẹ ọkan lara awọn alajọgbele fun Baba Adeyemi, sọ pe awọn ọlọpaa tilẹ halẹ mọ awọn baba yii ki wọn to gbe wọn lọ. O ni wọn ko ṣe wọn jẹjẹ rara.
Bẹẹ lo ni wọn ko gba awọn araale laye lati da si ọrọ naa ti wọn fi gbe awọn baba meji naa lọ.
Bakan naa ni ẹnikan toun naa ko darukọ rẹ, amọ ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, sọ pe:
"Wọn gbe Baba lọ si agọ ọlọpaa Agbomire, pẹlu ẹnikan to wa ki wọn laaarọ.
"Wọn ko gbe Mama Adeniyi lọ ni tiwọn, amọ iṣẹlẹ naa ṣoju mama, o si ti mu jinni-jinni ba wọn bayii."
Ile awọn Baba Adeniyi naa ni iroyin sọ pe o wa ni ojule kẹta , Adeniyi Dynasty, lẹyin ile ẹkọ ẹkọṣẹ ọwọ, loju ọna Road Safety, Ogbomoso niluu Oyo.
Ṣe ofin Naijiria fi aaye gba ki wọn gbe ẹbi ẹni ti wọn fẹsun kan?
Latigba ti iroyin ti jade pe wọn ti fọlọpaa gbe Baba Adeyemi ni ọpọ eeyan ti n beere pe ṣe ofin fi aaye silẹ fun ninawọ gan baba, iya, iyawo, ọmọ tabi ẹbi rẹ kankan ni?
Ọpọ eeyan lo n sọ pe to ba jẹ lori ẹsun ti Adeniyi funra rẹ ti ni oun gba lati jẹjọ ni wọn tun gbe baba rẹ si, pe eyi ko tọna labẹ ofin.
Ninu alaye rẹ to ṣe fun iwe iroyin Punch lori ọrọ yii, Amofin agba lorilẹede Naijiria, Femi Falana (SAN), sọ pe ko si aaye fun ofin lati mu ẹlomiran fun ẹsun ẹnikẹni.
Falana sọ pe: " Wọn ti mu baba naa. Ko si idi kankan labẹ ofin lati mu ẹnikan fun ẹnikeji. Ọkunrin naa ti ṣeleri lati farahan ni kootu, ki ni wọn tun mu baba rẹ fun?"
Bakan naa ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro nilẹẹ Naijiria (NBA) naa koro oju si mimu ti wọn mu Baba Adeyemi.
Aarẹ NBA, Mazi Afam Osigwe (SAN) pẹlu awọn agbejọrọ agba miin nilẹ Naijiria, kilọ pe ofin Naijiria ko faaye gba mimu ẹbi eeyan ki ẹni ti wọn fẹ ba rojọ gan-an le yọju si wọn.
Ohun kan ṣoṣo ti wọn ni ofin fi le fi aaye silẹ lati mu Baba Adeyemi ni ti baba funra rẹ ba jẹ afurasi, tabi ẹni to ni nnkan kan pẹlu ẹsun to wa nilẹ naa.
O fi kun un pe o ye ki kaluku fi idi ododo ọrọ yii mulẹ, ki wọn si mọ idi ti ọlọpaa ṣe gbe baba ti ọmọ rẹ lẹjọ lọdọ ijọba.
Ijọba naa lo si wa nipo alaye bo ṣe wi, lati ṣe fun araalu lori ọrọ yii.
Ikọ ọlọpaa, lati ẹka FCID ni iroyin sọ pe wọn gbe Baba Adeyemi lọ, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i sọ nnkan kan lori rẹ lasiko ti a pari iroyin yii.
Gbajabiamila ni oun le pe Adeyemi lẹjọ koun si beere N10bn fun ẹsun ipaniyan, abẹtẹlẹ
Olori oṣiṣẹ lọfiisi Aarẹ, Femi Gbajabiamila ti ni o ṣee sẹ ki oun gbe igbesẹ ipẹjọ ti yoo la biliọnu mẹwaa naira lọ fun Ọmọọba Adeniyi Adeyemi, nipa bo ṣe ni oun mọ nipa ipaniyan, owo ẹyin atawọn ẹsun iwa ọdaran mi-in.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch to fi iroyin naa lede ṣe wi, lẹta kan ni wọn ni Gbajabiamila kọ lọjọ kẹfa , oṣu Keje ọdun 2026 yii, eyi ti 'Kemi Pinheiro, (SAN), buwọ lu fun olori oṣiṣẹ lọdọ ijọba apapọ naa.
Femi Gbajabiamila kọ lẹta igbẹsẹ naa lẹyin ipade oniroyin kan ti wọn ni Adeyemi pe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Nibi ipade naa ni iroyin ti sọ pe Adeyemi ni Gbajabiamila beere ipin tirẹ ninu owo ileeṣẹ PFIPC to di ẹjọ bayii.
Ileeṣẹ yii ni ijọba apapọ ni oun ko mọ nipa rẹ, amọ ti Adeyemi sọ pe o ba ofin mu, to si gba ilana to yẹ lọdọ ijọba apapọ kọja.
Nibi ipade oniroyin naa ni iroyin sọ pe Adeyemi ti ni Gbaja gba lara owo to di ẹjọ bo tilẹ jẹ pe oun funra rẹ kọ lo tẹwọ gba a, ṣiṣe aṣilo ọfiisi rẹ ati ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Iroyin sọ pe Adeyemi tun ṣapejuwe Gbajabiamila bii apaayan nibi ipade naa.
Ki lo de ti Gbajabiamila fẹ gbe igbesẹ yii?
Awọn ọrọ yii ni Gbajabiamila ni ki Adeyemi ko jẹ, titi kan awọn fidio tabi ohùn ẹnu ti wọn ka silẹ to n ba Gbajabiamila lorukọ jẹ.
Wọn ni ko tọrọ aforiji ninu iwe iroyin marun-un, o kere tan, ko si ṣe bẹẹ lori awọn ẹka ayelujara ti wọn ti pin fọnran ipade oniroyin naa.
Bakan naa ni olori oṣiṣẹ lofiisi Aarẹ n beere pe ki Adeyemi kọwe adehun pe oun ko ni i kọ nnkan kan mọ nipa Gbajabiamila.
Lẹta naa ka ẹsun mẹsan-an to ni Adeyemi fi kan Gbaja, lara eyi ti I ṣe pe Gbajabiamila beere ida mejidinlaadọta (48%)ninu owo ileeṣẹ tijọba apapọ pe ni ayederu yii, to to N12.5bn
Ati pe o tun gba N400m latọwọdọwọ ninu ileeṣẹ naa.
Agbejọrọ fun Gbajabiamila ṣapejuwe awọn ẹsun ti Adeyemi fi kan onibaara rẹ bii irọ gbuu ati ibanilorukọjẹ.
Gbajabiamila funra sọ ninu lẹta naa pe oun ko foju kan Adeyemi ri, debi toun yoo ba a ṣe gbogbo ohun to ka si oun lẹsẹ.
"A fun ọ ni wakati mejilelaadọrin lati ṣe ohun to yẹ bi o ba ti gba lẹta yii
Gẹgẹ bi lẹta naa ṣe wi, wakati mejilelaadọrin ti i ṣe ọjọ mẹta ni Gbajabiamila fun Adeyemi lati ko gbogbo ohun to sọ naa jẹ, ai jẹ bẹẹ, yoo foju ba kootu.
O gbọdọ tọrọ aforiji loju iwe iroyin marun-un ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Owo to to N10bn ni Gbaja yoo beere fun bi wọn ṣe wi,bi Adeyemi ba kuna lati ṣe ohun ti wọn fẹ laaarin ọjọ mẹta.
Bẹẹ ni Adeyemi yoo tun jẹjọ ibanilorukojẹ pẹlu bi wọn ṣe sọ.