You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìdájọ́ tó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin láàyè láti máa wọ hijab lọ ilé ẹ̀kọ́
Ile ẹjọ kotẹmilorun to kalẹ silu Ibadan ti wogile igbẹjọ ti awọn ẹlẹṣin ibilẹ ati awọn obi awọn ọmọ mọkanla to jẹ ẹlẹṣin Musulumi gbe lọ ile ẹjọ lati faye gba wiwo hijabu ninu ile ẹkọ International school to wa ninu faṣiti ilu Ibadan.
Igbejọ naa lo bẹẹrẹ lati ọdun 2019 nile ẹjọ giga ti ipinlẹ Oyo ko to de ile ẹjọ kotẹmilorun tí ilu Ibadan lọjọ kejilelogun oṣu karun ọdun 2024 pẹlu nomba ipẹjọ m/423/19 , ati CA/IB/336/24.
Nigbati o n gbe igbejọ rẹ kalẹ, Adajọ àgbà ti ile ẹjọ kotẹmilorun ti ilu Ibadan Biobele Georgewill ṣalaye pe, ile ẹjọ naa fidi rẹ mulẹ wi pe ile ẹkọ International school Ibadan (ISI) kii ṣe ile ẹkọ ijọba, bo tilẹ jẹ wi pe inu fasiti ilu Ibadan to jẹ ti ijọba apapọ lọ wa.
O fidi rẹ mulẹ wi pe nitori ile ẹkọ naa n san owo awọn oṣiṣẹ rẹ lai jẹ wi pe ijọba apapọ lọ n san an fi han wi pe ile ẹkọ aladani niiṣe.
Biobele tún tẹsiwaju wi pe, gbogbo akẹkọọ ile ẹkọ naa lo ti tọwọbọ iwe adehun ṣaaju ki wọn to gba wọn wọle gẹgẹ bi akẹkọọ ni ile ẹkọ ọhun wi pe, awọn yoo tẹle ilana ati ofin ile ẹkọ naa.
O ni eyi ko faye gba ki awọn oniṣẹṣe tabi ẹlẹṣin Musulumi wọ hijabu tabi ki wọn wọ ileke to rọ mo ẹṣin wọn.
Nipa sisan owo itanran millionu Kan fun awọn akẹkọọ mọkanla ti ile ẹjọ fẹsun kan ile ẹkọ ISI pe wọn ti mọle, adajọ pasẹ ki wọn san ọwọ itanran ẹgbẹrun lọna igba naira.
Adajọ Biobele sọ siwaju si pe, ofin orilẹ-ede Naijiria faye gba ki onikaluku mọ ẹtọ rẹ gẹgẹ bii ofin, ṣugbọn ofin naa ko faye gba ki awọn ẹlẹṣin miran tapa si ilana ati iwe adehun ti wọn ti fọwọ si ṣaaju kí wọn to gba wọn gẹgẹ bii akẹkọọ ile ẹkọ naa.
"A fara mọ idajọ ile ẹjọ"
Yinka Akintunde, to jẹ ọga ile ẹkọ International school Ibadan ni ile ẹkọ naa yoo tẹlẹ ilana ati abajade igbẹjọ ọhun.
Oni lootọ ni wi pe awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ti tọwọ bọ iwe adehun lati tẹlẹ ofin ati ilana ile ẹkọ naa, ṣugbọn pẹlu idajọ ile ẹjọ, awọn ko ni ṣe idẹyhẹsi ẹsin kankan.
O rọ awọn obi lati mu awọn ọmọ wọn wa si ile ẹkọ naa, o tun ṣeleri lati maṣe yan awọn ẹlẹṣin Islam tabi awọn oniṣẹṣẹ jẹ ninu ọgba ile ẹkọ wọn.
Kilo tiṣẹlẹ sẹyin?
Awọn obi kan nile ẹkọ International School Ibadan, ISI, lo wọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ati ti fasiti Ibadan lọ siwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ pẹlu ẹsun pe wọn fi ẹtọ awọn akẹkọbinrin kan lori wiwọ ibori hijab dun wọn lọdun 2018.
Nigba ti wọn gbe ile ẹkọ naa lọ si ile ẹjọ awọn ẹsun mẹta ni wọn fi kan ile ẹkọ ọhun, awọn ẹsun nani: ki ile ẹjọ naa fi idi ẹtọ ọmọniyan awọn akẹkọbinrin ọhun lati wọ ibori hijab mulẹ, ẹbẹ keji ni ki ile ẹjọ paṣẹ pe bi wọn ṣe se ti awọn akẹkọọ to wọ hijab wọ yara iyaweka mọle fun ọpọlọpọ wakati ko bofin mu.
Bakan naa ni wọn tun n fẹ ki ile ẹjọ naa o gba awọn akẹkọ ọhun laye lati ṣamulo ẹtọ wọn ninu ẹsin to ba wu wọn.
Ọdun 2024 ni ile ẹjọ giga ti ipinle Oyo paṣe pe ki awọn akẹkọọ Musulumi maa wọ hijab nilẹ ẹkọ naa, ohun naa lọ fa ti awọn ẹlẹṣin abalaye naa ṣe n pe fun gbigba awọn ọmọ awọn to jẹ akẹkọọ naa laaye lati maa wọ awọn aṣọ to farapẹ ẹṣin wọn lọ si ile ẹkọ ki wọn si ya yara kan sọtọ fun wọn lati maa ṣe ijọsin wọn ninu ile ẹkọ ọhun.