Ifá kìlọ̀ fáwọn olóṣèlú tó fẹ́ dupò gómìnà l'Osun, àlàyè rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn alakoso Iṣẹṣe nipinlẹ Osun ti rọ gbogbo awọn adije fun ipo gomina nipinlẹ naa lati ma ṣe ọrọ eto idibo to n bọ lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ọdun yii ni bo o-ba-o-pa a.

Ẹgbẹ naa ti orukọ wọn n jẹ Traditional Religion Worshippers Association of Osun State (TRAWSO), ṣekilọ yii lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

TRAWSO labẹ aarẹ wọn, Dokita Oluseyi Atanda,sọ pe awọn ri ikilọ naa loju odu, lasiko ti wọn n d'Ifa lori eto aabo ati alaafia fun idibo gomina to n bọ lọna l'Osun.

Wọn fi kun un pe awọn tun ba Ifa ni gbolohun lori ijinigbe to n ṣẹlẹ ni Naijiria ati ọna abayọ si I kaakiri ipinlẹ.

Wo Odu to gàte fun awọn oludije naa bi TRWASO ṣe sọ

Aarẹ TRWASO, Dokita Oluseyi Atanda, jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn ọjọgbọn nidi ẹsin ibilẹ ni wọn wa nibi eto tawọn ti d'Ifa ọhun, to fi mọ Oloye Ifayemi Elebuibon to jẹ Araba Awo ipinlẹ Osun.

O ni Ifa fi ye awọn pe awọn oludije ati oloṣelu gbọdọ le gba iwọsi ati abuku mọra lasiko eto idibo to n bọ naa, lati le gba alaafia ati iṣọkan laaye.

Atanda sọ pe Ifa tun n sọ fawọn pe awọn nilo lati wure fun alaafia lasiko ati lẹyin idibo, ati pe gbogbo ohun ti Ifa ni kawọn ṣe ṣaaju lawọn ti ṣe ko ma baa si wahala tabi iṣoro.

"Ifa sọ pe idagbasoke yoo de ba ipinlẹ Osun, Osun yoo dide lati tàn lasiko iṣejọba to n bọ, ṣugbọn ẹnikẹni to ba gbegba oroke ni ẹni to jẹ pe o ni ifẹ araalu, to si gba iwọsi ati abuku mọra.

"Ifa fi ọkan wa balẹ pe nipa igbagbọ, ifọkantan ati agbọye, eto idibo to n bọ lọna ko ni i gba itajẹ silẹ.

"Ifa sọ pe otitọ ni pe gbogbo eeyan ni ọrọ wahala to n ṣẹlẹ lori ọrọ idibo naa n kọ lominu.

"Ifa ni ki gbogbo awọn alẹnulọrọ, oloṣelu ati ọmọ ipinlẹ Osun ma ṣe jokoo lori gegele, bi ko ṣe pe ka ko ipa tiwa gẹgẹ bi ọmọ ilu, lati le jẹ ki eto idibo yii lọ ni irọwọ-irọsẹ nipinlẹ Osun."

Aarẹ ẹgbẹ awọn Oniṣeṣe Osun naa lo ṣalaye bẹẹ.

Nipa ti wahala to n fojoojumọ ṣẹlẹ lẹka aabo, Aarẹ TRWASO sọ pe:

"Ifa ṣekilọ fun gbogbo awọn oludije sipo gomina lati ma ṣe jẹ ko di eyi ti wọn n pa ara wọn le lori.

"Igbesẹ yii le dana sun ipinlẹ Osun. Ifa rọ gbogbo araalu, lai ni i ṣe pẹlu ẹsin onikaluku, lati gbadura fun awọn oloṣelu, lati ṣe suuru, nitori pe Ọlọrun nikan lo n fi eeyan sipo."

Bakan naa lo tun rọ gbogbo awọn ọba alaye ti wọn ti ṣatilẹyin fun ọmọ oye kan tabi omiran lati ma ṣe jẹ ki aṣa bajẹ, ati pe gẹgẹ bi olori aṣa ati iṣẹṣe, ki wọn ko ipa wọn gẹgẹ bii baba fun gbogbo oloṣelu.

"Ifa sọ pe wura ni ọrọ Ifa ti a kọ sita, o pẹ tabi o ya, gbogbo rẹ lo maa wa si imuṣẹ. Fun idi eyi, o ṣekilọ fun gbogbo eeyan ati ijọba, paapaa awọn to wa lẹka eto iṣẹ agbẹ lati maa gbaradi fun iyan.

"Ẹbọ ti Ifa ni ka ru ateyi tawọn oriṣa yoku beere ni TRWASO ti ṣe fun tẹru tọmọ."

Tẹ o ba gbagbe, nnkan ko fararọ lẹka oṣelu ipinlẹ Osun lẹnu lọọlọ yii, pẹlu bi rogbodiyan to mu ẹmi eeyan lọ ṣe waye lawọn agbegbe kan niluu Osogbo.

Awọn eeyan padanu ẹmi ninu rogbodiyan lawọn ilu bii Ilobu, Ikire ati Esa Oke pẹlu, eyi ti ko ṣẹyin ikọlu awọn janduku oloṣelu bi iroyin ṣe sọ.