Inú gbogbo èèyàn ìpínlẹ̀ Osun ló dún sí ìdájọ́ tó fààyè gba Accord láti díje, Adeleke ní wọ́n ń fẹ́ - Ìjọba Osun

Oríṣun àwòrán, Gov. Ademola Adeleke
Lẹyin ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun ti paṣẹ pe ẹgbẹ oṣelu Accord atawọn yooku ti ile ẹjọ giga sọ pe wọn ko le dije ninu idibo to n bọ yii yoo kopa, ijọba ipinlẹ Osun ti sọ ero ọkan rẹ lori idajọ naa ati igbese to kan.
Agbẹnusọ fun Gomina Ademola Adeleke, Olawale Rasheed to ba BBC News Yoruba sọrọ lori idajọ naa sọ pe ki i ṣe gomina nikan ni idajọ ọhun dun mọ, bi ko ṣe gbogbo ọmọ ipinlẹ Osun pata.
"Idajọ ile ẹjọ giga yẹn ko tiẹ bofin mu latilẹ"
Ninu alaye agbẹnusọ Gomina Adeleke naa lo ti ni:
"Idajọ akọkọ yẹn ko ba ofin Naijiria mu,idajọ abẹ ile ni. Ikeji ni pe o tun tapa si idajọ to ti wa nilẹ nile ẹjọ to tun ga . Gbogbo wa l'Osun ti mọ pe irọ ni."
O ni eyi ni Gomina ṣe fi atẹjade sita, pe ki araalu fi ọkan balẹ, ki wọn ma ṣe ja, nitori orukọ Accord yoo wa lori iwe idibo loṣu Kẹjọ ti idibo yoo waye.
"Mo fẹẹ fi da yin loju pe ki i ṣe Gomina nikan ni inu wọn dun si idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun, gbogbo eeyan ipinlẹ Osun ni inu wọn dun si i."
Agbẹnusọ gomina naa fi kun alaye rẹ pe ọpọ eeyan lo fẹran Gomina Adeleke, ti wọn si fẹ ko jẹ pe oun ni yoo maa tẹsiwaju nipo rẹ.
"Araalu fẹran Adeleke, oun ni wọn fẹ ko maa tẹsiwaju ninu iṣejọba Osun."
Agbẹnusọ gomina lo ṣalaye bẹẹ.
A ti bẹrẹ ipolongo idibo, gbogbo aye lo ri i bi ero ṣe pọ to nibi iṣide eto wa
Olawale fi kun un alaye rẹ pe ikọ ipolongo ibo fun Gomina Adeleke ti bẹrẹ ikede naa lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, nibi ti Gomina funra rẹ ti kede awọn erongba rẹ.
"Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ni idibo yoo waye. Accord yoo wa nibẹ lati dije, araalu yoo si wa nibẹ lati dibo fun ẹni ti wọn fẹ."
Olawale Rasheed lo sọ bẹẹ.
O fi kun un pe ero rẹpẹtẹ lo wa nibi eto naa, eyi to fi han pe gomina Adeleke ni awọn eeyan Osun n fẹ bo ṣe sọ.
"A ko ni i huwa janduku, ile ẹjọ naa la o maa dojukọ lori ohun gbogbo to ba n ṣẹlẹ"
Gẹgẹ bi Agbẹnusọ Gomina Osun naa ṣe wi lori igbesẹ ti wọn yoo maa gbe bi ọrọ yii ṣe n lọ, o ni ijọba ti ko fẹran janduku ni ijọba Gomina Adeleke.
O fi kun un pe ko sohun to le ṣẹlẹ, ile ẹjọ ni Gomina Adeleke yoo maa lọ lati yanju ọrọ.
" A ko ni i huwa janduku kankan, ijọba to fẹran alaafia ni ti Gomina Ademola Adeleke, ile ẹjọ ni a o maa gbe ohun gbogbo lọ lati yanju.
"Ofin la o fi yanju gbogbo ohun to ba ku, a tun maa waa fibo yanju ẹ lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ, kawọn eeyan lọ dibo fun ẹni to ba wu wọn.
" Ko nilo kawọn eeyan maa yinbọn tabi ki wọn maa ja, iwe idibo yoo wa lọwọ ẹnikọọkan, ki wọn lọ dibo fun ẹni to ba wu wọn."
Olawale Rasheed lo sọ bẹẹ.
Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba àpapọ̀ ti sanwó ìjọba ìbílẹ̀ Osun tó dẹjọ́? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Osun State Government
Awuyewuye lori owo awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun ti n waye tipẹ, pẹlu bi ijọba apapọ ko ṣe sanwo naa si asunwon ti Gomina Ademola Adeleke n fẹ labẹ ofin.
Ọpọ igba ni gomina naa ti sọ pe owo ara oun loun fi n sanwo fawọn oṣiṣẹ to wa labẹ ijọba ibilẹ, latigba ti ijọba apapọ ko ti i sanwo naa si aaye to yẹ.
Ẹ o ranti pe ọrọ bẹrẹ si I fẹju lorii ta lo yẹ nipo awọn olori kansu ninu awọn PDP igba naa atawọn APC ti ijọba apapọ tilẹyin.
Ọrọ naa pada de kootu, o si di ohun ti ile ẹjọ da, pe o lodi fun ijọba apapọ lati gbẹsẹ le owo ijọba ibilẹ l'Osun.
Amọ lẹnu ojo meloo kan yii ni iroyin bẹrẹ si i jade, pe ijọba apapọ ti sanwo naa si asunwọn ti Adeleke n fẹ.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti iroyin yoo jade bẹẹ amọ ti yoo pada ja si irọ.
Lati mọ otitọ to wa nidii ọrọ naa lọtẹ yii, BBC Yoruba kan si ijọba ipinlẹ Osun lati ṣalaye, Agbẹnusọ fun Gomina Adeleke, iyẹn Olawale Rasheed si ṣalaye pe:
"Loootọ ni ijọba apapọ ti sanwo naa to le ni 300b, amọ…"
Nigba to n ṣalaye ọrọ naa laaarọ Ọjọru, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, Agbẹnusọ Gomina Osun naa sọ pe:
"Nnkan to ṣẹlẹ nipa owo kansu ni pe ijọba apapọ ni awọn ti san an, wọn wa ni pe ko sohun to kan awọn mọ.
"Ṣugbọn akanti to yẹ ki wọn sanwo si ni eyi ti ijọba ipinlẹ ba fi lelẹ labẹ ofin, awọn eeyan naa ni yoo jẹ ẹni to le gba owo jade, awọn bii olootu eto inawo ipinlẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
" Ofin ipinlẹ wa lo sọ bẹẹ, awọn to yẹ ki wọn ṣi akanti naa labẹ ofin niyẹn.
"Ṣugbọn nigba ti UBA fẹẹ ṣi akanti, ayederu ni wọn lọ gba lọdọ awọn alaga 'Yes or No'.
" Awọn alaga ti mo n pe bayii ni awọn alaga ti kootu ti le pe wọn ko lẹtọọ lati wa nipo mọ, amọ ti wọn ṣaa yari, ti wọn joye Akintola taku pe awọn ko lọ.
"Eyi ni ijọba ipinlẹ Osun ṣe gbe UBA lọ si kootu, pe akanti ti ko ba ofin mu ni won sanwo si, ọwọ ijọba Adeleke ko to owo naa.Enikẹni to ba si fọwọ kan owo naa lati ita, o le lo ja, owo olowo lo na.
Ibi tọrọ de duro
Gẹgẹ bi Olawale Rasheed ṣe ṣalaye lorukọ ijọba Osun, o ni ijọba apapọ ti sanwo, ṣugbọn UBA n ṣe apade alude laaarin rẹ pẹlu awọn alaga ti kootu ti le lọ.
"UBA naa pada lọ si kootu, pe awon ko na owo yẹn, o wa nibẹ, ati pe awọn tọrọ kan kọwọ bọwe, owo naa le ni 300b.
"Ijọba ipinlẹ Osun gba pe irọ ni wọn n pa, nigba ti ile ẹjọ ti ni awọn alaga yẹn ko lẹsẹ nilẹ, ohun to yẹ ki wọn ṣe ni ki wọn pe awọn eeyan ti ofin fọwọ si lati jẹ alakooso, ki wọn le mọ nipa rẹ.
"Awọn bii Olootu inawo ipinlẹ Osun, Olootu ẹka iṣejọba, lo yẹ ki wọn ṣi akanti yẹn, wọn a le maa sanwo awọn tiṣa atawọn mi-in to ba tun lẹtọọ si i."
Agbẹnusọ Gomina Adeleke naa sọ pe nigba ti wọn ko jẹ ko ri bẹẹ ni Adeleke ṣe n sanwo awon tiṣa, awọn oṣiṣẹ eleto ilera abẹle, oṣiṣẹfẹyinti atawọn mi-un lati bii ọdun kan aabọ sẹyin.
Igbesẹ to kan
"Nisinyi ti kootu ti dajọ pe awọn alaga yẹn ko lẹsẹ nilẹ, ti wọn ko si ni asiko lori itẹ mọ, ati pe wọn ko tiẹ lẹtọọ lati tiẹ pe ẹjọ ọhun gan-an, ijọba Osun ti gba idajọ naa sọwọ.
"Gomina yoo wa ba awọn agbofinro sọrọ, yoo si kọ lẹta si UBA naa, pe awọn alaga ti wọn n ba ṣe yẹn ko lẹsẹ nilẹ, ile ẹjọ ti sọ pe wọn ko ba ofin mu.
Eyi ni yoo jẹ ka ri i pe awon alaga ti araalu dibo yan lo waa gba ori aga, ti wọn si lẹtọọ lati gba owo yẹn."
Bẹẹ ni Olawale Rasheed, Agbẹnusọ Gomina Ademola Adeleke wi.
Ìdí tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fi ṣẹ́wélé àṣẹ adájọ́ tó ní kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Oriyomi, Adeleke àti Atiku kúrò nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X/Atiku Abubakar/X/Ademola Adeleke/X
Ilẹ ẹjọ kotẹmilọrun ti ṣẹwele aṣẹ ile ẹjọ giga apapọ l'Abuja to ni ki ajọ eleto idibo INEC yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu ADC, Accord, ZLP, AA ati APP kuro ninu awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo to n bọ.
Igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta ti Adajọ A. B. Mohammed dari bu ẹnu ẹtẹ lu bi Adajọ Peter Lifu ile ẹjọ giga apapọ l'Abuja ṣe dajo tako aṣẹ ile ẹjọ to jade lọjọ kejilelogun oṣu Karun un to kọja; eyi to sọ pe ko gbọdọ gbe igbesẹ lori ẹjọ to wa niwaju rẹ.
Awọn adajọ mẹtẹẹta naa sọ pe iwa to tako eto idajọ ni Adajọ Lifu hu pẹlu idajọ ti o gbe kalẹ.
Igbimọ oludajọ naa ni nnkan ti Adajọ Lifu ṣe tako ilana eto idajọ ati iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.
''Igbesẹ ile ẹjọ giga lati gbe idajọ kalẹ lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti paṣẹ idaduro lori ọrọ naa jẹ iwa to ko kudiẹ kaato eyi to lodi si ilana eto idajọ.
Koda, ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti sọ pe iru adajọ to ba huwa bayii ko yẹ lati maa ṣiṣẹ adajọ tori iwa jagidijagan ni eleyii tumọ si ninu eto idajọ.
Ile ẹjọ ni lati maa gbiyanju ki orukọ wọn ma bajẹ, ile ẹjọ kotẹmilọrun ni aṣẹ lori nnkan ti ile ẹjọ giga ba n ṣe lori ọrọ to ba wa niwaju rẹ.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun si le paṣẹ lati ri wi pe gbogbo nnkan lọ ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin.
Idi niyii ti ile ẹjọ yii fi ṣẹwele aṣẹ ile ẹjọ giga apapọ to ni ki ajọ INEC yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu marun un kuro ninu akọsilẹ rẹ,'' igbimọ oludajọ ṣalaye.
Ṣaaju ni ajọ eleto idibo INEC funra rẹ ti sọ fun ile ẹjọ wi pe idajọ ti Adajọ Lifu gbe kalẹ jẹ iyalẹnu foun.
Koda, INEC tun sọ pe ninu iwe iroyin loun ti ri iroyin naa ka tori ile ẹjọ giga ko sọ nnkan foun nipa idajọ naa.
Ajọ eleto idibo Naijiria ni oun mọ nipa aṣẹ ile ẹjọ to jade lọjọ kejilelogun oṣu Karun un, eyi to ni ile ẹjọ giga ko gbọdọ tii gbe idajọ kalẹ lori ọrọ to wa niwaju rẹ bayii.
Ni bayii, orukọ ẹgbẹ oṣelu maraarun un ADC, Accord, ZLP, AA ati APP tọrọ kan si wa ni akọsilẹ INEC titi ti igbẹjọ ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn pe yoo fi waye.
Ẹgbẹ́ òṣèlú Adeleke àti Oriyomi fapá jánú lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ní kí INEC yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oriyomi Hamzat/Adeleke
Ẹgbẹ oṣelu ADC ati Accrod ti bu ẹnu atẹ lu idajọ ile ẹjọ giga kan niluu Abuja to ni ki ajọ eleto idibo, INEC, fa orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu naa yọ ninu akọsilẹ rẹ nitori wọn ko ba ofin mu.
Lara awọn to bu ẹnu atẹ lu idajọ naa ni gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun to juwe idajọ ọhun gẹgẹ bii aṣilo ẹka eto idajọ ni Naijiria.
O ni ko si ohun ti yoo yẹ kikopa ẹgbẹ oṣelu Accord ninu eto idibo gomina ti yoo waye ninu oṣu Kejọ ọdun yii ni ipinlẹ naa.
Ẹgbẹ awọn aṣofin nigba kan ri, National Forum of Former Legislators, lo pe ẹjọ naa lati bere lọwọ ile ẹjọ pe ṣe INEC lẹtọọ lati wọgile awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn kuna lati ni awọn amuyẹ to wa ni abala 225A ti ofin ọdun 1999, eyii ti wọn ṣatunṣe rẹ lọdun 2022.
Nigba ti awọn alakoso ẹgbẹ Accord yoo sọrọ, wọn ni idajọ naa ko ba ofin mu latari pe o tako idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to ti waye ṣaaju.
Accord ni idajọ ọhun waye bo tilẹ jẹ pe idajọ kan ti waye ṣaaju, eyii to tako idajọ ile ẹjọ giga tuntun yii.
Ẹgbẹ oṣelu naa fi kun pe awọn ti bẹrẹ igbeṣe lati pe idajọ naa nija nile ẹjọ laipẹ.
Accord ni idajọ ọhun ko fo oun laya nitori oun jawe olubori ninu eto idibo sipo kansẹlọ to waye ni Jigawa lẹnu lọlọ yii.
Lẹyin naa ni wọn ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa atawọ alatilẹyin awọn ma foya nitori wọn yoo kopa ninu eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti ati ti ipinlẹ Osun to n bọ laipẹ yii.
Iwọyin ni awọn ẹgbẹ oselu ti ọrọ naa kan:
- African Democratic Congress (ADC)
- Accord Party (AP)
- Action Alliance (AA)
- Action Peoples Party (APP)
- Zenith Labour Party (ZLP
Ofin wo gan ni ile ẹjọ sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun tẹ loju mọlẹ?
Gẹge bii ohun ti adajọ to gbọ ẹjọ ọhun, Peter Lifu sọ, awọn ẹgbẹ oṣelu naa kọlu abala 225A ti ofin ọdun 1999 eyii ti wọn ti ṣe atunṣe si.
Abala ofin naa fun INEC lagbara lati wọgile orukọ ẹgbẹ oṣelu ninu iwe rẹ
- Ti wọn ba kuna lati jawe olubori ninu eto idibo ni ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ tabi ijọba ibilẹ.
- Ti wọn ba kuna lati ko ida 25% ibo ni ipinlẹ kan lasiko idibo Aarẹ, atawọn amuyẹ mii.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn to pe ẹjọ ọhun sọ, awọn ẹgbẹ oṣelu naa kuna lati ni awọn amuyẹ naa ninu awọn eto idibo to waye lẹnu lọlọ yii.
Ile ẹjọ ti wa paṣẹ ki INEC yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu naa kuro ninu iwe rẹ, o tun paṣẹ ki INEC ma jẹ ki wọn kopa ninu eto idibo ọjọ iwaju bii eto idibo to n bọ lọdun 2027.
Ilé ẹjọ́ ní kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Atiku, Oriyomi àti ẹgbẹ́ mẹ́ta mii kúrò nínú àkọsílẹ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X/Atiku Abubakar/X
Ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja ti paṣẹ fun ajọ eleto idibo INEC pe ko yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu ADC, Accord ati ẹgbẹ oṣelu mẹta mii kuro ninu awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo 2027 to n bọ.
Awọn ẹgbẹ oṣelu mẹta toku ni ẹgbẹ APP, ẹgbẹ oṣelu AA, ati ẹgbẹ ZLP.
Adajọ Peter Lifu lo paṣẹ naa nile ẹjọ giga apapọ l'Abuja lọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹfa yii.
Ṣaaju ni igbimọ awọn aṣofin tẹlẹri ti beere pe ki ile ẹjọ sọ boya ajọ eleto idibo INEC lagbara labẹ ofin lati yọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ba kuna lati ṣe nnkan ti abala 225A iwe ofin orilẹede Naijiria sọ kuro, eyi to wa ni ibamu pẹlu atunṣe ofin eto idibo Naijiria ti ọdun 2022.
Igbimo awọn aṣofin tẹlẹri naa sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un yii ti kuna lati maa tẹsiwaju gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria.
Lara awọn nnkan amuyẹ tawọn aṣofin naa sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa kuna lati ni, ni ida 25% ibo nipinlẹ kan lasiko eto idibo aarẹ to kọja.
Amuyẹ mii ni pe awọn ẹgbẹ oṣelu yii gbọdọ ni aṣoju kan ti araalu dibo yan yala ni ijọba ibilẹ tabi ipinlẹ tabi nile aṣofin agba l'Abuja.
Awọn olupẹjọ naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin yoku fidirẹmi ninu ibo gbogbogbo ọdun 2023 ati ninu atundi ibo to waye debi wi pe wọn ko ni aṣoju kankan ti araalu dibo yan.
Awọn aṣofin tẹlẹ ri naa sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin mii ṣe wa lara awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹ dije ninu eto idibo to n bọ lodi sofin orilẹede Naijiria ati ofin eto idibo.
Lẹyin naa ni wọn rọ ile ẹjọ pe ki o yọ orukọ awọn ẹgbẹ marun un naa kuro ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Bakan naa tun ni awọn olupẹjọ tun rọ ile ẹjọ lati fofin de awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa wi pe wọn o gbọdọ kopa ninu ipolongo ibo ati eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Wọn tun rọ ile ẹjọ wi pe ko paṣẹ fun ajọ INEC pe ko gbọdọ ni ibaṣepọ kankan pelu awọn ẹgbẹ naa mọ.
Idajọ yii yoo ṣakoba fun Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, to fẹ dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC ninu eto idibo ọdun 2027.
''Awọn aṣoju ijọba to wa lode ni ko fẹ ki ADC kopa ninu ibo 2027''
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu ADC to jẹ ẹgbẹ Atiku Abubakar ti sọ pe ile ẹjọ fẹ lo ara rẹ lati ṣakoba fun ijọba awaarawa pẹlu idajọ ti ileẹjọ apapo l'Abuja gbe jade.
Ẹgbẹ naa sọ pe idajọ ti Adajọ Peter Lifu gbe kalẹ buru jai, o si le da rogbodiyan silẹ lagbo oṣelu.
Ẹgbẹ ADC sọ ninu atẹjade to fi sita pe idajọ ile ẹjọ giga apapọ naa tako iwe ofin Naijiria.
Lori ọrọ ti awọn aṣofin tẹlẹ ri naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin mii pe wọn o ni amuyẹ lati wa lara awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo to n bọ, ADC sọ pe ajọ INEC funra rẹ ti fontẹ lu ẹgbẹ ADC loṣu Karun un to kọja.
Ẹgbẹ ADC ni kii ṣe ajọ kan lo maa sọ pe ki INEC yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu kan kuro ninu akọsilẹ ẹgbẹ oṣelu.
Wọn ni ọrọ ofin lọrọ naa, eyi ti INEC funra rẹ gan an ko si ri ẹsun kankan ka si ẹgbẹ naa lẹsẹ.
ADC ni nnkan to yani lẹnu ni wi pe adajọ Lifu mọ wi pe ẹjọ kan wa nile ẹjọ kotẹmilọrun tẹlẹ eyi ti ko tii ni iyanju ki o to gbe idajọ tiẹ kalẹ.
Ẹgbẹ oṣelu Atiku ni ọrọ naa ti lọwọ oṣelu ninu, wọn ni awọn agbodegba ẹgbẹ APC lo wa nidii ọrọ naa.
Ninu ọrọ tiẹ, oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat, ti sọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ọrọ idajọ ileẹjọ giga apapọ l'Abuja to ni ki wọn yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu naa kuro ninu akọsilẹ INEC ti le ni iyanju.
Oriyomi ni ile ẹjọ ko le da nnkan tawọn araalu n fẹ duro.
Oriyomi sọ pe ẹjọ naa wa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tẹlẹ, ati pe awọn n reti nnkan idajọ ile kotẹmilọrun lori ọrọ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2



























