Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo buwọ́lu òfin gbogbo ogúnjọ́ oṣù Kẹ́jọ bíi àyájọ́ Ìṣẹ̀ṣe láì yẹ̀

Bi ayẹyẹ ọdun Iṣẹṣẹ to jẹ ti awọn ẹlẹsin ibilẹ ṣe n waye lonii ogunjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026, ijọba ipinlẹ Oyo ti kede pe oun ti ṣofin ti yoo sọ ayẹyẹ naa di ohun ti yoo maa waye lọdọọdun lai yẹ ni gbogbo ogunjọ oṣu Kẹjọ.
Kọmiṣanaa fun eto Igbafẹ ati Aṣa nipinlẹ Oyo, Wasiu Olatunbosun, lo fidi eyi mulẹ fawọn akọroyin nibi ayẹyẹ naa to waye ni papa iṣere Adamasingba, niluu Ibadan.
O ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Oyo ti fi ontẹ lu u lati maa ya gbogbo ogunjọ oṣu Kẹjọ sọtọ fawọn ẹlẹsin abalaye, kawọn naa le mọ pe wọn ṣe pataki lawujọ.
"Gomina Makinde ti buwọ lu abadofin naa"
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna fun eto Igbafẹ ati Aṣa nipinlẹ Oyo naa ṣe wi, o ni Gomina Seyi Makinde ti buwọlu abadofin naa lẹyin to ti gba ile igbimọ aṣofin kọja.
Eyi lo ni yoo tun fi ayajọ ọdun Iṣẹṣẹ mulẹ si i nipinlẹ Oyo.
Olatunbosun ni ayajọ naa yoo tun fi idi ẹwà, aṣa ati ìṣẹ Yoruba mulẹ ṣi i, ki ẹṣin abalaye ma baa parun lo si wa fun gẹgẹ bo ṣe wi.
O fi kun un pe bi iṣakoso Gomina Makinde ṣe n ti ẹnu bọpo lọ yii, awọn ijọba to ba n de lẹyin rẹ naa yoo le maa tẹsiwaju ninu aba ọdun Iṣẹṣẹ to buwọlu yii.
Ìjọba àpapọ gbọ́dọ̀ ka àwa ẹlẹ́sìn àbáláyé náà ṣí-Omowe Fayemi Ifakayode

Ninu ọrọ gbajumọ ẹlẹsin ibilẹ kan nibi ayẹyẹ ọdun naa, iyẹn Ọmọwe Fayemi Ifakayode, o ni ijọba apapọ naa ni lati da ẹṣin Abalaye mọ.
Ọmọwe Fayemi sọ pe ninu iwe ofin orilẹ ede Naijiria, gbogbo ẹṣin ti wọn ṣe lorilẹ-ede yii ni ofin damọ.
O ni ṣugbọn o ṣeni laanu pe ẹṣin Kristẹni ati ẹṣin Islam nìkan ni ijọba faaye gba ju, ti wọn si da ẹyẹ si ẹsin Abalaye.
"Ni gbogbo ibi ti ijọba apapọ ba ti n ṣe eto kan tabi omiran, adura nilana Kristẹni ati ti Musulumi nikan ni wọn maa n gba, wọn ki i fi ti Iṣẹṣe si i.
"Awọn adari ẹṣin Kristẹni ati Musulumi maa n ṣe bii pe awọn nikan ni wọn ni orile-ede Naijiria, eyi ko si yẹ ko ri bẹẹ."
Bẹẹ ni Omowe Ifakayode wi.
O ni Iṣẹṣe ki i ṣe nnkan mi-in bi ko ṣe ṣiṣẹ nnkan nilana igba iwaṣẹ, nigba ti wọn ṣẹda iran Yoruba.
Ifakayode sọ pe igba diẹ naa lo ku ti ẹsin Iṣẹṣe naa yoo fi duro ni aaye to yẹ ẹ, nitori awọn ti n gbe e larugẹ ju ti tẹlẹ lọ.
Awọn ẹgbẹ, OniSango, Eleegun atawọn ẹgbẹ miran lọ ko ra jọ sibi ayẹyẹ ti ọdun yii lati fi ẹwa ati aṣa ẹṣin wọn hàn.
Lara awọn ori ade lati ipinlẹ Oyo to pejọ sibi ayẹyẹ ọdun Iṣẹṣe ti ọdun yii ni:
Olubadan ti ilẹ Ibadan ti wọn ran aṣoju wa, Eleruwa ti ilu Eruwa, Aseyin ti ilu Iseyin ati awọn baale lati ọpọ agbegbe nipinlẹ Oyo.



























