Àwọn ọmọ Nàìjíríà míràn tó há sí South Africa ti balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed l'Eko

Awọn ero lati inu baalu wọ suẹta dudu ni papakọ ofurufu l'Eko
Àkọlé àwòrán, Àwọn toto ṣẹ̀ṣẹ̀ dé
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awọn ọmọ Naijiria ti wọn le lọọdunrun to n gbe lorileede South Africa ti balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa nipinlẹ Eko, lẹyin ifẹhonuhan awọn araalu lati le gbogbo awọn ajoji pada si ibi ti wọn ti wa. Latigba ti ikọlu ati ifẹhonuhan ọhun ti bẹrẹ ni ijọba Naijiria ti bẹrẹ igbesẹ lati ko awọn ọmọ Naijiria to ha si orilẹede naa pada sile lati dena ijamba to ṣeeṣe ko kọlu wọn. Ṣaaju ni agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere, Kimiebi Ebienfa, ti jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan ọọdunrun-le-ni-mẹjọ ti wa ninu ọkọ baalu lati agogo mẹfa aabọ aarọ oni, Ọjọru, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Keje.

O ni agogo mọkanla aabọ ni wọn yoo balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa nipinlẹ Ekoo.

Oṣiṣẹ baalu mẹta ati awọn ero marunlelọọdunrun ni wọn ba baalu naa de.

Ileeṣẹ naa sọ pe awọn wọnyi ni wọn wa ni ipele to kẹyin, ati pe ipele karun-un ni awọn ti ijọba ṣe iranwọ lati ko pada naa.

Agbẹnusọ awọn ọmọ Naijiria to n gbe lorileede South Africa, Akindele Olunloyo sọ fun BBC lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii pe awọn ọmọ Naijiria to le lọgọrun kan ni wọn ṣi wa nilẹ lati pada sile wọn.

"A ṣi ni awọn to pọ nilẹ to ti n wu lati pada sile lori ibẹrubojo ikọlu to n waye lorileede South Africa.

Ọpọ awọn eeyan to fi mọ awọn ọmọde ni wọn ti wa nita gbangba ti wọn n sun si ni papakọ ofurufu Pretoria, nibi ti nnkan ko ti rọrun fun wọn, paapaa lasiko otutu yii."

Ẹgbẹ naa wa rawọ ẹbẹ si ijọba Naijiria ati awọn ijọba ipinlẹ, to fi mọ awọn ẹlẹyinju ọmọ Naijiria lati dide iranlọwọ pajawiri fun wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ South Africa jẹ ko di mimọ pe awọn to le ni ẹgbẹrun kan ni wọn ti forukọsilẹ lati kuro nibẹ, iyẹn ni kete ti eto kiko awọn eeyan kuro ninu oṣu Kẹfa.

Ọpọ orileede, to fi mọ Ghana, Naijiria, Uganda ati Kenya ni wọn ti bẹrẹ sii ko awọn eeyan wọn kuro, ni kete ti ikọlu ifẹhonuhan naa bẹrẹ.

Awọn olufẹhonu han naa n sọ pe ijọba awọn gbọdọ ṣabojuto gbogbo ẹnubode lori bi wọn ṣe n le awọn ajoji kuro, pẹlu bi wọn ṣe fẹsun kan awọn ajoji pe wọn lọwọ ninu airiṣẹṣe, ati iwa ọdaran to pọ lorileede wọn.

Wọn dunkooko pe ọsẹ-ọsẹ ni awọn yoo maa jade lati fẹhonu han titi digba ti gboggo ajoji yoo fi kuro patapata.

Ifẹhonuhan yii di di aawọ laaarin ijọba South Africa ati awọn ijọba ilẹ Afrika kan.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe awọn ajoji lati orileede miran ni awọn olufẹhonu South Africa n ṣe ikọlu si, bo tilẹ jẹ pe ijọba ilẹ naa sọ pe ko ri bẹẹ.

Iroyin awọn eeyan ti wọn pa lori rogbodiyan yii wa nita, ṣugbọn awọn alakoso South Africa sọ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ṣi n pe fun iwadii ijinlẹ ti ko lọwọ oṣelu tabi ijọba ninu.

Ṣugbọn ṣa, ifẹhonuhan ọhun sọ eso rere gẹgẹ bi ijọba South Africa ṣe kede pe awọn ajoji to le lẹgbẹrun mẹtalelaadọta ni wọn ti ko pada sibi ti wọn ti wa latigba ti wọn ti bẹrẹ eto naa lọsẹ marun-un sẹyin.

Ijọba ti ṣeleri lati dide iranlọwọ fun gbogbo awọn to ṣẹṣẹ de lati South Africa naa

Minisita fọrọ eto idajọ ati idagbasoke iwe ofin, Mmamoloko Kubayi sọ pe igbesẹ dida awọn ajoji naa pada sile wọn ti jẹ ki awọn ṣawari gbogbo awọn ti ileeṣẹ ọlọpaa ti n wa tipẹ lori ẹsun iwa ọdaran.

Ṣugbọn sibẹ, ijọba Naijiria ti ṣeleri lati dide iranlọwọ fun gbogbo awọn to ṣẹṣẹ fe naa, nipa kiko wọn pada sile layọ ati alaafia, ti wọn yoo si pada si aarin awujọ, gẹgẹ bo ti yẹ.

Ajọ to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri nilẹ Naijiria, (NEMA) ti wa fidi rẹ mulẹ pe awọn yoo fọwọsowọpọ pẹlu awọn ajọ ati ileeṣẹ tọrọ naa kan, lati rii pe gbogbo awọn to ṣẹṣẹ de yii, ni wọn ri iranwọ to yẹ gba, ko to di pe wọn pada sọdọ mọlẹbi wọn.

Lara awọn iranwọ ti ajọ NEMA n ṣe ni fifi ọkọ gbe awọn eeyan pada si ipinlẹ wọn, ati bi awọn oṣiṣẹ eleto aabo yoo ṣe tẹle wọn fun aabo to pe ye lati papakọ ofurufu.

Bakan naa, ijọba Naijiria tun sọ pe ki gbogbo awọn to ṣẹṣẹ de yii fi orukọ silẹ fun iṣẹ to wu wọn lati ṣe, tabi dukia ti wọn fi silẹ nibi ti ogun ti le wọn kuro, pẹlu bi wọn ṣe ṣeleri iranwọ lati ọdọ ijọba South Africa.

Adele alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ ọmọ Naijiria lorileede South Africa, Alexander Ajayi ti sọ lori amohunmaworan pe ijọba ilẹ naa ti bẹrẹ gbogbo eto akọsilẹ okoowo ati dukia ti awọn ọmọ Naijiria fi silẹ lorileede awọn.

Nigba ti awọn naa n sọrọ, ijọba South Africa ti sọ fun gbogbo eeyan ti okoowo wọn ni ipalara lori rogbodiyan ifẹhonuhan lori awọn olugbe ti ko ni akọsilẹ, lati fi to ileeṣẹ to n ri sọrọ idasilẹ okoowo, Department of Trade, Industry and Competition leti.

Bakan naa ni wọn tun sọ pe ki gbogbo awọn ti ikọlu naa kan ninu rogbodiyan awọn to n gbe lorileede wọn lọna aitọ fi to ajọ naa ileeṣẹ naa leti fun akọsilẹ.

Ile igbimọ aṣofin Naijiria fun Ijọba South Africa ni gbedeke ọsẹ meji lati fi ṣe iwadii ikọlu to ṣẹlẹ

Ile igbimọ aṣofin orileede Naijiria ti fun igbimọ to n ri sọrọ ilẹ okeere ni gbedeke ọsẹ meji lati iṣẹ iwadii kikun lori awọn ọmọ Naijiria ti wọn ṣe ikọlu si lorileede South Africa, ti wọn si tun sọ igbesẹ ti ijọba naa gbọdọ gbe lẹyin iwadii. Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti awọn aṣofin jiroro lati fidi awọn ileeṣẹ ilẹ South Africa ni Naijiria mulẹ labẹ ofin, ati lati fi okoowo wọn ṣe iranwọ fun awọn ọmọ wọn padanu dukia ati okoowo lori ikọlu to ṣẹlẹ nibi ifẹhonuhan to waye. Awọn aṣofin kọ aba naa. Igbakeji Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Barau Jibrin, to ṣagbatẹru ijokoo naa rọ awọn aṣofin lati duro de abajade iwadii, ko to di pe wọn gbe igbesẹ kankan. "Ẹ jẹ ki igbimọ to n ri sọrọ ilẹ okeere ṣe iwadii wọn na. Naijiria lo n lewaju ilẹ Afrika. A ni lati jẹ aṣaaju rere. Nigba ti a ba ri okodoro ti a n fẹ gba, a le gbe igbesẹ. Bi iwadii naa ko ba si tẹ wa lọrun, igba naa la ṣẹṣẹ maa tẹle ohun ti ẹ sọ," igbakeji Aarẹ sọ bẹẹ. Aba mẹrin ọtọọtọ ni ile igbimọ aṣofin fẹnuko si, eyi to nii ṣe pẹlu bi ijọba Naijiria ṣe n beere fun akọsilẹ aridaju wi pe ijọba South Africa yoo ṣabojuto eto aabo awọn ọmọ Naijiria, ti wọn si gbọdọ fi oju awọn to ṣe ikọlu winna ofin. Wọn tun sọ pe ileeṣẹ ile okeere, ileeṣẹ NiDCOM nilẹ South Africa gbọdọ ṣe akọsilẹ awọn iṣẹlẹ to la iku, ifarapa, iyọnipo, fifi eeyan si atimọle lọna aitọ ati pipadanu okoowo lọ, lojuna lati fun onikaluku ni ẹtọ rẹ labẹ ofin.