Kí ló dé táwọn obìnrin fi tú jáde ṣe ìfẹ̀hónúhàn l'Osun? Ohun tí a mọ̀ rèé

Ọgọọrọ obinrin tu jade ṣe ifehonuhan niluu Osogbo ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Osun lọjọ Aje ọjọ kẹwaa oṣù Kẹjọ yìí latari rogbodiyan to n ṣẹlẹ lemọlemọ ṣaaju eto idibo gomina opin ọsẹ yii.
Ọkan lara awọn oluwọde naa sọ pe ninu ibẹru ati ifoya ni ipinlẹ Ọsun wa lọwọlọwọ.
O ni ẹru si n ba awon obinrin lati jade ni ọjọ idibo.
O le ni ẹgbẹrun kan awọn Obinrin nipinlẹ Ọsun to tu jade sita fun ifẹhonuhan ọhun.
Wọn ni rogbodiyan, ija,ipaniyan ati dida Ilu ru to n ṣẹlẹ to gẹ.
Awọn Obinrin naa ni ọpọ ninu wọn mu iwe ilewọ dani eyi ti wọn kọ oriṣiriṣii akọle sibẹ.
Titilola Adeleke ẹni to jẹ aya fun gomina Ademola Adeleke, naa ba awọn Obinrin jade fun ifẹhonuhan ọhun.
Ninu ọrọ rẹ ni asiko iwọde naa lo ti sọ pe awọn Obinrin jade sita lati ke si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati Aya Aarẹ Olurẹmi Tinubu ki wọn pe Ọga agba fun awọn Ọlọpaa Orilẹede Naijiria Olatunji Disu, lati pèsè eto aabo to peye fun awọn Oludibo ni ọjọ Kẹẹdogun osu Kẹjọ yii.
Ati pe wọn tun fẹ ki awọn Ọlọpaa ṣiṣẹ wọn ki wọn si ma ṣegbe lẹyin oloṣelu kankan lasiko idibo naa.
Awọn oluwọde naa tun fẹ kawọn ọlọpaa jẹ ki awọn oludibo dibo wọn fun ẹni to ba wu wọn lati dibo fun.
Arabinrin Awolowo Ayobola, ninu ọrọ tirẹ naa lo ti sọ pe, ẹru awọn janduku ati Ọlọpaa lo n ba awọn ni akoko idibo.
Ọ wa rọ Aarẹ Tinubu lati wa ojutuu si ọrọ rogbodiyan ati ipaniyan to n ṣẹlẹ lojoojumọ nipinlẹ Ọṣun ati lati ba awọn to yẹ sọrọ ki alaafia le jọba ni akoko idibo.
Arabinrin Fatima Abubakar, ẹni to jẹ aja fun ẹtọ awọn Obinrin sọrọ lori bi ko ṣe si alaafia ninu Ilu ati Ipinlẹ Ọsun lapapọ.
O ni ohun to buru ju lawujọ ni pe, ki eeyan ma ni anfaani ati ominira lati ṣe ẹtọ tabi ojuṣe rẹ lawujọ.
Arabinrin Fatima wa rọ gbogbo awọn oloselu lati fi aye gba alaafia torí eleyii lọ le mu ki awọn oludibo jade sita lati dibo fun ẹni to ba wu wọn.
Kọmisọna ọlọpaa fun eto idibo naa, Samuel Etaifo, wa fi awọn oluwọde naa lọkan balẹ pe gbogbo ohun ti wọn n ṣe iwọde le lori ni ile iṣẹ Ọlọpaa ti gbọ.
O ni awọn si ti setan lati gbogun ti ẹnikẹni to ba fẹ dá wahala silẹ lọjọ ìdìbò tabi lẹyìn eto idibo.


























