You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Atiku Abubakar: Owó wọ àkáǹtì mi fún ìpolongo ìbò, mi ò mọ bó ṣe débẹ̀ o
Atiku Abubakar, Igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan to tun n dupo aarẹ lọwọ yii ninu ẹgbẹ NDC, ti ke gbajare pe owo kan ti wọ akanti adani oun bayii, bẹẹ oun ko mọ ẹni to fowo ọhun ranṣẹ sibẹ.
Atiku ni o jọ pe awọn kan ti wa ọna kan tọwọ bọ akanti oun ni.
Ki lo ṣẹlẹ ?
Lọjọ Ẹti, ọjọ keje oṣu Kejọ ọdun 2026 yii ni Atiku Abubakar kede owo naa ninu atẹjade ti Agba Oludamọran pataki rẹ, Phrank Shaibu, fi sita.
Atẹjade naa sọ pe ẹni ti Atiku o mọ ri lo fi owo ranṣẹ to si kọ akọle yii si i "Contribution Electioneering Campaign."
Itumọ eyi ni Didasi ipolongo ibo.
"Atiku tabi ikọ ipolongo rẹ ko tọrọ owo, bẹẹ ni wọn ko mọ ẹnikẹni tabi ajọ kankan to wa nidii owo ti wọn san si akanti naa lọna aitọ.
"Awọn ohun to rọ mọ owo ti wọn san si akanti naa ko fi eeyan lọkan balẹ rara, nitori akanti adani ti ko si nita fun gbogbo eeyan lati mọ ni.
"Eyi gan-an lo n kọ wa lominu, bawo ni awọn ta o mọ ri ṣe ri nọmba akanti adani ti ko si nita naa."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade Atiku beere.
Oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu NDC naa sọ pe bi wọn ba le ri nọmba ikọkọ iru oun toun ti jẹ igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ gba, ti wọn si sanwo sibẹ bii eyi, a jẹ pe ewu n bẹ loko longẹ fawọn araalu lasan nipa aabo owo wọn.
Atẹjade naa tun kede pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn eeyan to ni anfaani si nọmba naa lo gbabọde, ti wọn fun awọn to sanwo sibẹ.
Amọ ju gbogbo ẹ lọ, Atiku rọ awọn eeyan Naijiria lati ma ṣe gba kawọn ọta oṣelu ba orukọ oun jẹ bi ibo ọdun 2027 ṣe n sunmọle.
"Wọn ti pete iru eyi ri ti ko bọ si i, wọn yoo tun lulẹ lọtẹ yii naa ni."
Bẹẹ ni Atiku wi.
O ni oun ko ni i tori awọn nnkan bawọnyi yi ipinnu ododo toun ni lati dari Naijiria pada, oun si ni esi si iṣoro Naijiria lọwọ, oun yoo yanju rẹ boun ba le depo aarẹ.
Amọ ọpọ eeyan lo ti n fi ero ọkan wọn han lori ayelujara nipa owo ti Atiku ni o wọ akanti oun yii.
Wọn n sọ pe itanjẹ lasan ti yoo jẹ ki araalu ro pe olootọ eeyan ni Atiku ni ọkunrin naa n gbe jade.
Ọpọ eeyan lo n sọ pe ete oṣelu kan ni Waziri Adamawa tun n ba bọ, wọn ni ko ti i jẹwọ ododo to wa nidii owo to kede naa.