Baálé ilé fi ìyàwó àtàwọn ìbejì tí wọ́n bí sílẹ̀ ní South Africa, sá wá sí Nàìjíríà, àlàyé rẹ̀ rèé

    • Author, Makuochi Okafor
    • Role, BBC Africa
    • Reporting from, Lagos
    • Author, Thomas Naadi
    • Role, BBC Africa
    • Reporting from, Accra
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Fun ọkunrin ọmọ Naijiria kan to ṣẹṣe ti South Africa de latari bi wọn ṣe n le awọn ajeji danu lorilẹede naa, iyẹn Ọgbẹni Richard Itoro, ko mọ asiko ti yoo tun foju kan awọn ibeji to bi si orilẹede naa mọ, tabi boya yoo tilẹ tun ri wọn mọ.

Nigba ti ko si aabo mọ, to jọ pe awọn to n ṣigun le wọn ni South Africa le debi ẹmi rẹ lo sa kuro niluu naa lai mu iyawo rẹ dani, bẹẹ ni ko ko awọn ọmọ naa pẹlu.

Itoro, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta (47) fi okoowo to n ṣe ni South Africa silẹ ni Johannesburg, o wọ ọkan lara awọn baaluu to ko awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ wale, o si balẹ si orilẹede abinibi rẹ loṣu Kẹfa.

Ọkan lara awọn eeyan to koju idaamu lọwọ awọn eeyan South Africa ni ti Itoro yii, iwa to le ba ajọṣepọ orilẹede South Africa pẹlu awọn ilẹ Adulawọ mi-in jẹ si ni ọpọ eeyan n sọ pe awọn eeyan ilu naa n hu.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan lo ti fi ilu naa silẹ fun wọn lati oṣu meji sẹyin.

"O ni mi lara lati fi ẹni to jẹ ọrẹ mi tootọ silẹ." Itoro fomije ṣalaye ọrọ fun BBC nipa iyawo rẹ to jẹ ọmọ orilẹede South Africa, nigba to ranti bo ṣe fi ilu naa silẹ.

Laaarin ọdun mẹẹẹdogun to fi wa nibẹ, o ti di agba ọjẹ ninu okoowo mọto tita nibẹ , o ra ile kan sibẹ o si bẹrẹ si i ṣe abiyamọ pẹlu iyawo rẹ. Amọ ni bayii, gbogbo iyẹn ti lọ.

Itoro koju idaamu, amọ bẹẹ naa ni wọn tun ṣe fun iyawo rẹ.

O ṣalaye pe alajọgbe awọn kan sọ fun iyawo oun pe: "Ọmọ Naijiria lo fẹ, gbogbo ẹyin tẹ ẹ fẹ ọmọ Naijiria yii, o yẹ ka fi ofin mu yin ni.

"Ọdalẹ ni yin, ẹ dalẹ̀ wa. Ma ba ọkọ rẹ lọ, kuro nibi."

Itoro ni eyi ya oun lẹnu pupọ.

"Idile mi ki i ṣe rẹpẹtẹ, kekere ni, eyi to rẹwa to si kun fun alaafia. Mi o ba ẹnikẹni fa nnkan kan pọ, amọ idaamu yẹn pọ ju.

"Bi mo ba wa sile ti mo bẹrẹ aye pada, o daa ju ki n wa nibi ti wọn ti n daamu mi lọ, ẹru n ba mi ki wọn ma pa mi." Itoro lo sọ bẹẹ..

''Wọn ko gba ki n mu iyawo atawọn ọmọ mi wọ Naijiria''

Ninu alaye Richard Itoro to n tẹsiwaju lo ti ni ẹka Nigerian High Commission to n ri si ọrọ naa ko gba koun mu iyawo atawọn ọmọ oun wọle si Naijiria nigba toun n bọ nile.

O ni niṣe lo jọ bii ẹni to n wo fiimu, bii ẹni to wọ ọkọ igbẹyin lati bọ lọwọ awọn ọta to yi i ka.

" O wu ki n le bẹ awọn eeyan to wa ni ẹmbasi yẹn pe ki wọn jọọ: Ki n sọ fun wọn pe 'Iyawo mi niyi, mi o le fi i silẹ pẹlu awọn ọmọ mi.' Amọ mi o ri iru ẹ ṣe.

"Bẹẹ ni ọkọ ti mo wọ bẹrẹ si i ṣi, to n gbera irinajo, o si da bii pe ki n ti sọ fun un tẹlẹ pe ko ma sunkun (iyawo rẹ)."

Awọn to n le eeyan jade ni South Africa yii wulẹ sọ pe awọn ajeji ti ko niwe igbeluu lawọn n le danu. Agbẹnusọ wọn to tun jẹ minisita fun Aṣa, Gayton McKenzie, to lewaju iwọde kan, fidi eyi mulẹ ṣinṣin.

"A sọ pe awọn brọda wa le wọle si South Africa lati awọn ilẹ ibomi-in, amọ ki wọn wa lọna ẹtọ, wa pẹlu iwe igbeluu rẹ".

Bẹẹ lo sọ fun BBC ninu ifọrọwerọ kan.

Amọ Itoro sọ pe boun ṣe wa niluu naa lọna to ba ofin mu to, wọn ko tori ẹ da oun si lọwọ ikorira ati ibaniṣe ọta. (O fi ẹda iwe to fun un lẹtọ lati maa gbe South Africa han BBC) .

Awọn alaṣẹ irinajo yii ni Naijiria naa fidi ẹ mulẹ, wọn ni Itoro nikan kọ ni ọrọ rẹ ri bẹẹ.

"A ni akọsilẹ awọn ọmọ Naijiria to ni iwe to ba ofin mu lati duro ni South Africa, sibẹ, wọn kọlu wọn."

Minisita to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria, Sola Enikanolaiye lo sọ bẹẹ laipẹ yii lasiko ipade kan pẹlu Minisita ọrọ ilẹ okeere ni South Africa; Ronald Lamola.

Ọrọ naa tun le si i lọsẹ to lọ lọhun-un, lẹyin iku ọmọ Naijiria kan lasiko tawọn ọlọpaa South Africa mu un lori ẹsun oogun oloro. Ajọ aladaani kan ti n ṣewadii eyi.

Lamola ninu ọrọ rẹ sọ pe awọn to n ṣe ofin lọwọ ara wọn ni South Africa n doju ija kọ, o wa fi kun un pe Aarẹ Cyril Ramaphosa naa ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu lilo ofin rẹ lori iwọlejade arinrinajo.

Amọ pẹlu gbogbo ọna ti South Africa n gba lati pe ara rẹ ni ilu to nifẹẹ ajeji, ọpọ eeyan ni ko fi oju ire wo wọn mọ.

Bi awọn aworan kan tawọn eeyan n ri lori iwa wọn lori ayelujara ko tilẹ fi gbogbo ara jẹ otitọ, ki i ṣe gbogbo rẹ lo ri bẹẹ. Ọkan wa to jẹ ti ọkunrin ọmọ orilẹede Ghana kan, Emmanuel Asamoah, o mu ariwo dani gan-an loṣu Kẹrin.

Nigba ti Emmanuel Asamoah kuro ni Ghana ni 2023, to morile South Africa, bi nnkan yoo ṣe daa fun un ju ti ibi to ti n bọ lo ba lọ.

Ẹni ọdun mẹtadinlogoji naa fi ibugbe rẹ si Soweto, nigberiko Johannesburg,iṣẹ aṣerunloge lo n ṣe. O bẹrẹ igbe aye rẹ nibẹ, ero rẹ si ni pe ọja ọla oun yoo daa lorilẹee Africa ti ọrọ aje rẹ tobi ju naa.

Amọ loṣu mẹta sẹyin, ọjọ iwaju ti Emmanuel n foju sun bẹrẹ si i yingin loju rẹ, nigba tawọn eeyan South Africa de ti wọn si ni ko maa lọ. Bi wọn ṣe koju rẹ naa wa ninu fidio ti wọn ka silẹ.

"Bi ẹyin eeyan yii ṣe n fi orilẹede yin silẹ lọ sibomi-in yii ko ṣiṣẹ mọ, a n jẹ ko ye yin pe a ko fẹ yin nibi, a fẹ tun ilu wa ṣe."

Obinrin kan lo n sọ bẹẹ fun Asamoah ninu fidio naa.

Asamoah ko ni ohun kan to le ṣe ju ko pada si Ghana lọ. Nigba to de si olu ilu Ghana ti i ṣe Accra loṣu Karun-un, o sọ fun BBC pe ẹru ṣi n ba oun pẹlu ohun toun koju naa.

"Wọn wa ba mi wọn si bẹrẹ si i ti mi... Wọn bẹrẹ si i beere ibeere oriṣiriṣi lọwọ mi wọn si n ṣe mi bo ṣe wu wọn… wọn ni ki n maa lọ sile, pe a n ba ilu awọn jẹ, pe nitori tiwa, awọn ki i jẹun, a tun n gba awọn ọrẹbinrin awọn."

Asamoah lo ṣalaye bẹẹ.

"Nipa ai si iṣẹ ni South Africa - o wa ni ida ọgbọn30% - wọn ri i bii ohun kan to n kona mọ wahala yii. McKenzie lo ṣalaye bẹẹ.

"Ko sẹni ti yoo maa bọ ọmọ ẹlomi-in nigba tawọn ọmọ tiẹ naa ko ti i jẹun. Awọn eeyan wa o riṣẹ ṣe."

Bẹẹ lo wi lati gbe awijarẹ rẹ lẹsẹ, to si tun ni awọn ti ko niwe igbeluu lawọn n le lọ.

Pada sọdọ Asamoah, ohun to ṣaa n sọ ni pe oun ni ami kan lori iwe irinna oun, to gba oun laye lati duro si South Africa.

"Emi o wọlu lai lẹtọọ. Ọna ofin ni mo fi wa ni South Africa. Tori ẹ ni mo ṣe sọ fun wọn pe wọn le mu mi lọ si agọ ọlọpaa, ka le lọ sọdọ awọn to n ri si igbeluu ka si fidi ẹ mulẹ." .

Amọ bo ṣe pada si Ghana yii, o ni oun ṣẹṣẹ bẹrẹ aye lakọtun ni.

Pẹlu iranlọwọ latọdọ oniṣowo ọmọ ilẹ Ghana kan, o ti bẹrẹ okoowo simẹnti tita bayii, o si pinnu lati ni ọjọ ọla ninu ọja yii.

"Ẹyin eeyan mi lọkunrin ati lobinrin ni South Africa, mo ti wa ni Ghana bayii o. Emi naa n tun ilu mi ṣe."

Bẹẹ ni Emmanuel Asamoah wi.

Bawọn ọmọ Ghana ṣe n pada wale yii n bi awọn alaṣẹ ilu naa ninu, minisita ọrọ ilẹ okeere wọn, Samuel Okudzeto Ablakwa, ṣalaye fun BBC pe awọn South Africa ti gbagbe bi awọn ilẹ Africa yoku ṣe ran wọn lọwọ lati ṣẹgun Apartheid to pari ni 1994.

Ni ti Itoro Richard, ọmọ Naijiria, ilu Eko lo wa, to n ṣafẹri iyawo atawọn ọmọ rẹ to fi silẹ ni South Africa.

"Ko dẹrun rara. Amọ a maa n sọrọ lojoojumọ, ọkan mi gbọgbẹ.

Ireti wa, tori iyawo mi yoo darapọ mọ mi laipẹ, bi Oluwa ba ti gbe ọwọ mi soke.

Amọ ibanujẹ ni, mo padanu gbogbo nnkan."