Gbàjarè oo! Inú àpò àṣùwọ̀n owó orí ayélujára 'crypto' ni wọ́n n jí owó ìjọba ìbílẹ̀ pamọ́ sí báyìí – EFCC figbe ta

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣẹ owo ilu kumọkumọ nilẹ Naijiria, EFCC ti sọ pe inu apo aṣuwọn ori ayelujara ti ẹnikẹni ko le tọpinpin rẹ ni wọn n ji owo ijọba ibilẹ ko si bayii.
EFCC sọ pe nigba ti wọn ba wọ owo naa kuro ninu apo aṣuwọn ijọba ibilẹ sinu apo aṣuwọn ileeṣẹ aladani, ni wọn yoo to ṣẹṣẹ wọ sinu apo aṣuwọn crypto lori ayelujara, ki aṣiri ma ba a tu.
Alaga ajọ EFCC, Ola Olukoyede lo fidi aṣiri yii mulẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja.
"A ti gbẹsẹ le awọn apo aṣuwọn naa fun wakati mejilelaadọrin ri, lati le ṣe iwadii awọn ibi ti owo naa n lọ, ati ohun ti wọn fẹ fi ṣe ni pato"
Bo tilẹ jẹ pe Olukoyede ko darukọ awọn ijọba ibilẹ, ileeṣẹ ati awọn ipinlẹ tọrọ naa kan, sibẹ o sọ pe ajọ EFCC ko le gboju kuro ninu bi owo ilu ṣe n fo kaakiri lọna to nii fura si.
O ni ẹka ileeṣẹ wọn to n ri si ewu jibiti, iyẹn FRACD ti ṣawari awọn ọna ti owo ijọba n gba fo kaakiri lọna to mu ifurasi lọwọ.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe, awọn ti gbẹsẹ le awọn apo aṣuwọn naa fun wakati mejilelaadọrin ri, lati le ṣe iwadii awọn ibi ti owo naa n lọ, ati ohun ti wọn fẹ fi ṣe ni pato.
Ohun tó n bà mí lọ́kàn jẹ́
Ọga agba EFCC naa sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ foun nigba ti awọn eeyan ba n pe fun ori oun, lori awọn igbesẹ ti ajọ EFCC ba gbe lati gbogun ti iwa jibiti.
Ninu ọrọ rẹ, o ni, "Nigba ti a ba kofiri owo to n fo kaakiri lọna to nii fura si, a maa dide lati gbesẹ le e fun igba diẹ. Mo mọ pe ninu yin lo n beere fun ori mi," Olukoyede sọ bẹẹ.
"Wakati mejilelaadọrin la fi gbesẹ le owo naa. Ki wọn wa ṣalaye ibi ti owo naa n lọ, idi ti wọn fi n wọ owo naa. A ri bi owo ṣe n fo lati inu apo aṣuwọn ijọba ibilẹ sinu apo aṣuwọn ileeṣẹ aladani.
"Yatọ si eyi, a tun ṣakiyesi pe inu apo aṣuwọn ori ayelujara ti a mọ si 'cryptocurrency wallets' ni awọn owo naa lọ.
"Ṣe opopona ti ẹ fẹẹ ṣe niyẹn? Ṣe awọn araalu naa le jẹ anfaani ninu ọna lati wa owo ori ayelujara yii? Ṣe niṣe lẹ n sọ fun mi pe ki n di oju mi si iru nnkan bẹẹ? A jẹ wi pe ẹ ko nilo mi lori ipo yii niyẹn," alaga EFCC sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
"A kò lè káwọ́ gbera ki wọn maa ji owo ijọba"
Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe idagbasoke naa lo jẹ ki ajọ EFCC bẹrẹ igbesẹ lati ma ṣe duro de igba ti wọn ba n ji owo ilu, ko to di pe awọn dide, ati pe awọn nilo lati kọkọ da awọn owo naa duro, lati mọ ohun ti wọn wa fun, ati ibi ti wọn n lọ.
"Ki lo de ti a ṣe maa duro digba ti wọn ba ji owo ijọba? Ki lo de ti a ko le yi nnkan pada si bo ti tọ? Ohun pataki ti a si gbọdọ mu wa si ileeṣẹ ree," Olukoyede jẹ ko di mimọ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju eto idibo gomina nipinlẹ Osun to waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni ajọ EFCC gbesẹ le aṣuwọn ipinlẹ naa, lori ẹsun ti wọn fi kan ijọba nipa owo to n fo lọna ifurasi.
Ṣugbọn sibẹ, EFCC ko fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ Osun ni wọn ti ṣawari idagbasoke tuntun yii, bẹẹ si ni ko darukọ ipinlẹ miran pẹlu.
"Jìbìtì orí ayélujára tí kọjá 'Yahoo-Yahoo', wọn n lo awọn ọdọ lati ji owo ijọba sinu apo asunwọn Crypto"
Olukoyede tun fi kun ọrọ rẹ pe iwa jibiti ori ayelujara ti kọja ohun ti awọn eeyan mọ si Yahoo-Yahoo, pẹlu bo ṣe sọ pe wọn ti n lo awọn ọdọ bayii lati fi ji owo ilu ko pamọ sinu apo aṣuwọn ori ayelujara ti a mọ si 'cryptocurrency wallets'.
O sọ pe, "A ti wa ni ipo naa lorileede Naijiria bayii, leyi to jẹ pe awọn oṣiṣẹ ati aṣoju ijọba ti n ji owo ko, ti wọn si n ko o pamọ sinu apo aṣuwọn cryptocurrency.
"Ọpọ awọn adari ẹka ileeṣẹ ijọba ti a n ṣe iwadii wọn lọwọ bayii, ẹ ko le ri dukia gid ikan mọ wọn. Wọn n ji awọn owo yii ko, wọn n fun awọn akẹkọọ, awọn ọdọ. Kaakiri agbaye ni wọn ti n ṣi apo aṣuwọn ori ayelujara. Wọn a si ko awọn owo naa sibẹ laaarin wakati mẹrinlelogun.
"Owo naa n lọ soke okun. Wọn n rai le nibikibi lagbaye, wọn n ra awọn nnkan olowo nla to jọju. Awọn nnkan to n lọ nigboro lasiko yii ree."
"Àwa náà kò dúró, a ti gbe oju opo kalẹ lati tọpinpin apo aṣuwọn ori ayelujara, pẹlu awọn to ti forukọsilẹ ni Naijiria"
Olukoyede sọ pe igbesẹ yii, lo jẹ ki awọn naa ṣagbekalẹ ọna lati maa tọpinpin awọn owo ori ayelujara wọnyi, paapaa awọn eyi ti wọn ṣi nilẹ Naijiria, ti wọn si fi n ji owo ko.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o fidi rẹ mulẹ pe oju opo awọn dukia ori ayelujara to to ogoji ni awọn ti fun ni iwe aṣẹ, lẹyin agbeyẹwo ti wọn ṣe nipa wọn, ati agbara ti awọn ileeṣẹ naa ni.
"Ni bayii, awa naa ti ṣagbekalẹ oju opo ti a fi n tọpinpin apo aṣuwọn ori ayelujara yii, pẹlu awọn to ti forukọsilẹ ni Naijiria, ohun ti a n ṣe ree," o fi kun ọrọ ree.
Nigba to n tọka si awọn aṣeyọri ajọ naa lati bi ọdun mẹta sẹyin, Olukoyede sọ pe awọn ti gba ọpọ dukia ori ayelujara ti wọn fi jibiti ko jọ nipasẹ CBEX.
O ni ohun to n fun wọn ni ipenija bayii, ni bi wọn ko ṣe tii mọ awọn to wa nidi agbekalẹ CBEX naa.
"Nigba ti ẹ ba gba awọn dukia ori ayelujara wọnyi, nibo lẹ fẹẹ ko wọn si? Ko si otitọ. Idi ree ti a ko fi le maa tẹsiwaju bayii.
"EFCC lé ogójì òṣìṣẹ́ danù torí ìwà àjẹbánu"
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn oṣiṣẹ ti ko din ni ogoji ni ajọ naa ti le danu lẹnu iṣẹ, nitori iwa jibiti ti wọn ka mọ wọn lọwọ.
O ni laaarin ọdun meji aabọ si mẹta toun ti gba iṣakoso, loun ti ṣawari awọn oniwa jibiti ninu awọn oṣiṣẹ wọn, to si loun ko le gboju kuro lara wọn.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe pupọ ninu awọn ti wọn le danu yii, ni wọn ti n foju ba ile-ẹjọ, nigba ti wọn n ṣe iwe awọn yooku lọwọ lati kawọ pọyin rojọ niwaju ile-ẹjọ.



























