You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣé ọlọ́pàá fòfin de àwọn Amotekun, Iru-Ekun, Ọlọdẹ àti Fijilante lásìkò ìdìbò gómìnà Ọṣun
Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria ti sọ pe awọn ileeṣẹ aabo ibilẹ bii Amotekun, Iru-Ekun, Ọlọdẹ ilu tabi adugbo, to fi mọ awọn Fijilante ko ni i ṣiṣẹ lasiko eto idibo gomina ipinlẹ Osun.
Ọlọpaa sọ pe gbogbo awọn ileeṣẹ eleto aabo wọnyi, ati awọn miran ti wọn ko si labẹ akoso ijọba apapọ ni wọn ko ni lanfaani lati ṣiṣẹ aabo lasiko et idibo naa.
Ọga ọlọpaa pata nilẹ Naijiria, Olatunji Rilwan Disu lo ṣe ikilọ naa ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ agbẹnusọ wọn, Ani Iniedu l'Ọjọru, ọsẹ yii.
Opin ọsẹ ti a wa yii, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo gomina yoo waye kaakiri ipinlẹ Osun, nibi ti oludije mẹẹdogun yoo ti du ipo gomina kan ṣoṣo.
Gbogbo oludije patapata, awọn alatilẹyin wọn, to fi mọ awọn tọrọ kan patapata ni wọn ti wa ni igbaradi lati kopa nibi eto idibo gomina ọhun.
Ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe gbogbo ileeṣẹ eleto aabo kereje wọnyi ni wọn ko ohunkohun lati ṣe leyi to jọ mọ ọrọ eto idibo, yala nipa titẹle ohun elo idibo, didaabobo ibudo idibo, gbigbegi dina ati awọn miran.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun ṣe ikilọ fun gbogbo awọn oludije, ẹgbẹ oṣelu, awọn alatilẹyin, to fi mọ awọn alẹnulọrọ lati yago fun awọn iwa to le dabaru eto idibo alalaafia to yẹ ko waye l'Osun.
Ọga ọlọpaa sọ pe ẹnikẹni to ba n gbiyanju lati dabaru alaafia lasiko idibo nipa iwa ipa tabi jagidijagan yoo foju winna ofin to pọ, ti yoo si kabamọ nla.
Ninu atẹjade naa, Disu fidi rẹ mulẹ pe awọn ti kofiri oniruuru iwa ọdaran bii jiji apoti ibo gbe, ṣiṣe idunkooko, rira ibo, ṣiṣe ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ati awọn miran, eyi to lawọn ko ni faaye gba lọjọ naa.
O ni ati ẹni tọwọ tẹ, ati ẹni to ran wọn niṣẹ de-toru-toru ni wọn yoo jọ ko papọ lati foju wọn winna ofin lọna to yẹ, lai nii ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu tabi iru ẹni ti wọn jẹ.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe awọn ojulowo oṣiṣẹ aabo ti yoo ṣiṣẹ lọjọ naa ni ọlọpaa, ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tii ṣe DSS, Sifu Difẹnsi, Ẹṣọ aṣọbode, ileeṣẹ alabojuto ọgba ẹwọn, ẹṣọ aabo oju popona FRSC, ati awọn miran to jẹ tijọba apapọ.
Disu sọ pe gbogbo awọn ileeṣẹ aabo wọnyi ni yoo fọwọsowọpọ lọjọ naa lati wa kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn to so ipinlẹ Osun papọ.
O ni gbogbo aṣoju eleto aabo patapata ni yoo ni ibudo ati ẹkun idibo kọọkan lati bojuto ohun elo idibo, oṣiṣẹ eleto idibo, awọn awoye, oniroyin ati awọn oludibo lapapọ.
Fryo, olùdijé sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ PDP juwọ́ sílẹ̀ f'Adeleke
Oludije sipo gomina ipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Adedamola Adebayo lo ti kede wi pe oun ko du ipo naa mọ.
Adebayo tọpọ awọn eeyan tun n pe ni Fryo lo fi ikede naa sita, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Osogbo l'Ọjọru, ọsẹ yii.
Fryo sọ pe lati le jẹ ki eto idibo naa lọ, bo ti tọ, ati bo ti yẹ, paapaa lati faaye gba Gomina Ademola Adeleke lati pari awọn iṣẹ akanṣe to dawọ le lo fa erongba oun.
Ọkunrin naa ṣalaye pe boun ṣe juwọ silẹ yii, erongba oun ni lati ṣatilẹyin fun Adeleke.
O wa rọ gbogbo awọn alatilẹyin ati ololufẹ rẹ nidi oṣelu lati ṣatilẹyin fun Ademola Adeleke lati le pada sipo naa fun saa keji.
Kini Fryo tun sọ?
Fryo ni gbogbo kii ṣe pe oun da erongba naa ṣe, bi ko ṣe pe lẹyin oniruuru agbeyẹwo ati kikan si awọn agbaagba ati alẹnulọrọ, lawọn fẹnuko lati gbe igbesẹ naa.
"Lẹyin ọpọlọpọ agbeyẹwo ati kikan si awọn agbaagba ati alẹnulọrọ, mo pinnu lati ṣatilẹyin fun Sẹnetọ Ademola Adeleke ninu eto idibo gomina ipinlẹ Osun to n bọ lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026," Adebayọ sọ bẹẹ ninu ọrọ rẹ.
O ni ṣaaju asiko yii loun ti ba gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ PDP, awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn alẹnulọrọ sọrọ, to si ni gbogbo wọn lo fọwọ si ipinnu ọhun.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe o ṣee ṣe ki lara awọn alatilẹyin oun ma fọwọ si igbesẹ yii, to si le mu ki wọn binu, o rawọ ẹbẹ, to si sọ pe lara igbesẹ eto oṣelu awa-ara-wa ni.
Oludije PDP yii wa rọ gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu, oludije ati awọn alatilẹyin lati yago fun eyikeyi iwa ipa, idunkooko, ọrọ alufanṣa, ato awọn iwa miran to le dabaru alaafia lasiko eto idibo ọjọ Satide.
"Ipinlẹ Osun ga ju ẹnikẹni lọ. Ipinlẹ Osun ga ju ẹgbẹ oṣelu yoowu lọ. Bẹẹ si ni ipinlẹ Osun ga ju eto idibo yoowu lọ," Adebayo fidi rẹ mulẹ.
O rọ gbogbo eeyan lati yago fun iwa ibajẹ, to si ni ki onikaluku gba alaafia laaye, nitori pe eto idibo yoo waye, yoo si lọ, nigba ti awọn araalu yoo ṣi maa gbe papọ.
Àjọ INEC ṣe àtúntẹ̀ ìwé ìdìbò gómìnà l'Osun, ṣe àfikún orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP
Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ti kede sita pe awọn ti ṣe atuntẹ iwe idibo ti wọn yoo fi dibo nibi eto idibo gomina ipinlẹ Osun to fẹẹ waye lopin ọsẹ yii.
INEC sọ pe o pọn dandan fun awọn lati ṣe atuntẹ naa, pẹlu bi awọn ti ṣe fi orukọ oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP sinu orukọ awọn oludije.
Ninu atẹjade ti INEC fi sawọn oju opo wọn l'Ọjọru to kọja, wọn ni ayipada to wa ninu iwe idibo naa ni ti ẹgbẹ oṣelu SDP ti awọn ṣe afikun rẹ.
Wọn ni igbesẹ naa lo waye lẹyin idajọ ile-ẹjọ giga tiluu Abuja, leyi to ni ki awọn ri Olugbenga Ajala gẹgẹ bii oludije sipo gomina lẹgbẹ naa.
"Igbesẹ yii la gbe ni ibamu pẹlu idajọ ile-ẹjọ giga tiluu Abuja, ti wọn gbe kalẹ lọjọ kejilelogun , oṣu Keje, ọdun 2026, eyi ti nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/344/2026, laaarin ẹgbẹ oṣelu SDP ati Ọmọwe Francis Olugbenga Ajala lapa kan, ati ajọ eleto idibo INEC lapa keji," INEC sọ bẹẹ ninu atẹjade.
O sọ siwaju pe "Ile ẹjọ paṣẹ pe ki ajọ yii ri, ki wọn gba, ki wọn si fi orukọ Ọmọwe Francis Olugbenga Ajala sinu iwe idibo, oju opo ayelujara gẹgẹ bi oludije sipo gomina ipinlẹ Osun."
Akpabio, Aiyedatiwa, Uzodimma àtàwọn míìn balẹ̀ sílùú Osogbo fun àṣekágbá ìpolongo ìdìbo gómìnà Osun
Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba nilẹ Naijiria, Godswill Akpabio ti balẹ sipinlẹ Osun, ṣaaju eto idibo gomina to n bọ lopin ọsẹ yii.
Sẹnetọ Akpabio ati ikọ akọwọrin rẹ, pẹlu awọn bii alaga igbimọ ẹgbẹ gomina onitẹsiwaju, Hope Uzodimma; Monday Okpebholo tipinlẹ Edo ati Gomina Usman Ododpo tipinlẹ Kogi.
Oni Ọjọru, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni aṣekagba eto ipolongo idibo gomina nipinlẹ Osun, eyi tẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti ya sọtọ.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo gomina yoo waye nipinlẹ Osun, nibi ti gbogbo araalu, adije, awọn alatilẹyin oludije, to fi mọ awọn alẹnulọrọ yoo ti dibo yan gomina tuntun.
Bakan naa ni Gomina Lucky Aiyedatiwa tipinlẹ Ondo, aṣoju-ṣofin lẹkun Ikeja nipinlẹ Eko, James Faleke ni wọn ti wa l'Osun pẹlu, lati ṣagbatẹru oludije sipo gomina lẹgbẹ osẹlu APC, Bola Oyebamiji.