Ọmọ Naijiria méjì kú sọ́wọ́ ọlọ́pàá àti lásìkò ìkọlù ní South Africa, ìjọba àpapọ̀ fọnmú, bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Awọn oluwọde nilẹ South Africa n fi ẹhonu han sawọn ajeji to wa nilẹ wọn
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ileeṣẹ ọlọpaa orileede South Africa ti sọ pe otitọ ni pe awọn ọmọ ilẹ Naijiria meji ku siluu naa lasiko ti South Africa n le awọn ajeji Adulawọ kuro, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii kikun lori ohun to ṣokunfa iku wọn.

Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwadii, iyẹn Independent Police Investigative Directorate (IPID) sọ pe awọn tun bẹrẹ iwadii lori awọn ọlọpaa ilu Pretoria pẹlu, lẹyin ti wọn ṣeku pa ọmọ Naijiria kan.

Ajọ naa to n ṣe iwadii lori iwa awọn ọlọpaa sọ fun BBC lọjọ Aje pe ọsẹ to kọja ni wọn fi iroyin nipa iku ọmọ Naijiria naa torukọ rẹ n jẹ Iroegbu to awọn leti, ati pe iwadii ti n lọ lọwọ lorii rẹ.

IPID sọrọ yii lẹyin ti ijọba Naijiria fẹsun kan orileede South Africa pe wọn ṣeku pa awọn ọmọ ilẹ yii meji, lasiko ti wọn n ṣe ikọlu sawọn ajoji lorileede wọn.

Awọn eeyan n sọkakẹ ninu baaluu to gbe wọn de lati South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Atẹjade kan to jade ni ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere ni Naijiria sọ pe awọn ọlọpaa ni Tshwane Metro, lorilẹede South Africa ni wọn pa Emeka Charles Iroegbu ni Pretoria, lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2026.

Atẹjade naa ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Kimiebi Ebienfa buwọ lu lọjọ Aiku, ṣalaye pe awọn ọlọpaa kan naa ti pa ọmọ Naijiria kan, Nnaemeka Ekpeyong.

"A ṣi wa lori ẹjọ naa, wọn ko tii mu ẹnikẹni, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa mẹrin tọrọ naa kan ki i ṣaimọ fun ileeṣẹ ọlọpaa South Africa, (SAPS)."

Atẹjade ọhun sọ bẹẹ.

Ẹnikeji ti wọn ṣeku pa ni ileeṣẹ ilẹ okeere nilẹ Naijiria fi orukọ rẹ sita gẹgẹ bii Musa Yuana Joe, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Big Joe, ẹni ti wọn ṣe ikọlu si, ti wọn si pa a siwaju ṣọọbu rẹ to wa ni Witibank, Mpumalanga.

Nigba ti wọn n bu ẹnu atẹ lu iwa ipaniyan naa, ileeṣẹ ọhun sọ pe awọn ti bẹrẹ si i beere ibeere lori bi awọn kan ṣe n ṣeku pa awọn ọmọ Naijiria to n la kaka, ti wọn n ṣiṣẹ takuntakun nipakupa, pẹlu bi wọn ṣen pe wọn ni ọdaran."

Atẹjade naa tun ni awọn n beere ibeere lori eto aabo awọn ọmọ Naijiria ati awọn ọmọ orileede miran ti wọn n gbe ni South Africa.

Ileeṣẹ naa sọ pe pẹlu bi iṣẹlẹ naa ṣe n tẹsiwaju, "o fi han daju pe awọn eleto aabo, paapaa awọn ọlọpaa Tshwane Metro lọwọ ninu rẹ, iyẹn iwa to n fa oniruuru ibeere nipa ojuṣe ijọba ninu ofin agbaye."

Iṣẹlẹ ọhun, gẹgẹ bi ileeṣẹ naa ṣe sọ, lo waye laaarin ifẹhonuhan awọn ọmọ South Africa, ti wọn ti ṣaaju kiko awọn eeyan to to ẹgbẹrun mẹẹdogun pada si awọn orileede wọn.

Awọn olufẹhonu han nilẹ South Africa ti n sọ fun ijọba lati tubọ dide sọrọ awọn to n gbe lorileede wọn lọna aitọ.

Wọn ni awọn to n wa lati orileede miran lo n gba iṣẹ awọn ṣe, ti wọn si n jẹ anfaani iṣẹ ijọba ti ko tii to wọn lati ṣe.

IPID ṣalaye ohun to ṣẹlẹ sawọn ọmọ Naijiria meji naa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ko si atẹjade kankan lati ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere, to fidi rẹ mulẹ pe ohun ti ile ajọ alabojuto awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere sọ nipa iku awọn meji naa ko ri bi wọn ṣe sọ ọ.

Ju gbogbo rẹ lọ, IPID ṣalaye pe ohun to ṣokunfa iku Emeka Iroegbu ṣi n ru wọn loju. Ṣugbọn gẹgẹ bi iroyin ṣe gbe e, o ku "lasiko laasigbo pẹlu awọn ọlọpaa".

Ileeṣẹ naa sọ pe awọn ko nii fi idanimọ awọn to mu ẹsun naa wa fun wọn sita, ati pe ohun kan ṣoṣo ti awọn le sọ ni pato ni pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Lori iku Big Joe, eyi to ṣẹlẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Mpumalanga fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn kan lo ṣe ikọlu sii niwaju ṣọọbu ti wọn ti n ṣe irun lọṣọọ ni eMalahleni, ibi ti wọn n pe ni Witbank tẹlẹ, ti wọn si yinbọno fun un lọpọ igba, ko to di pe wọn na papa bora pẹlu ayọkẹlẹ sedan alawọ funfun.

Ọlọpaa sọ fun BBC pe awọn ko tii rọwọ to ẹnikẹni, ati pe ohun to ṣokunfa ikọlu naa ko tii han si awọn.

Ọlọpaa wa sọ pe ẹnikẹni to ba ni olobo ti wọn fẹẹ fun wọn lori ikọlu naa, ati pe bi wọn ṣe le mu awọn afurasi wa sọdọ awọn.

Awọn ọmọ Naijiria miran yoo kuro ni South Africa lọjọ Iṣẹgun

Ṣugbọn ṣa, ijọba ilẹ Naijiria sọ pe ipele awọn ọmọ Naijiria miran yoo kuro ni South Africa lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keje, oṣu Keje.

Minisita fọrọ ilẹ okeere, Bianca Odumegwu-Ojukwu, lo kede iroyin naa loju opo 'X' rẹ lọjọ Aje.

"Ọkọ baalu miran ti yoo ko awọn eeyan yoo kuro ni Johannesburg ni ọla, ọjọ keje, oṣu Keje, lati ko awọn eeyan wa sile," Odumegwu-Ojukwu kọ ọ bẹẹ.

Kiko awọn eeyan kuro naa yoo jẹ tuntun lara awọn igbesẹ ti ijọba Naijiria n gbe lati rii pe awọn ọmọ ilu to n gbe lorileede South Africa pada sile.

Ṣaaju asiko yii, ipele mẹrin awọn ọmọ Naijiria ni wọn ti pada sile lati ibẹrẹ oṣu kẹfa.

Minisita sọ pe ọkọ baalu naa to maa gbera pẹlu awọn to fẹẹ ko "yoo balẹ si South Africa lọjọ kẹwaa, oṣu Keje".

"Awọn eeyan wa ni lati ṣagbeyẹwo daadaa lati mọ daju boya wọn fẹẹ duro si South Africa, tabi wọn fẹẹ pada sile." Bẹẹ ni minisita naa wi.

"A n pe fun iṣẹ iwadii" – Ijọba Naijiria

Minisita to bu ẹnu atẹ lu pipa ọmọ Naijiria meji naa nilẹ South Africa ti wa pe awọn alakoso lati "tete ṣe iwadii iṣẹlẹ naa, ki wọn si rii daju pe wọn mu awọn to lọwọ si iṣẹlẹ naa wa siwaju ofin".

"Ko tii si awọn aridaju wi pe idagbasoke yoo de ba iṣẹlẹ naa," o sọ bẹẹ.

"Ohun to jẹ ilẹ Naijiria logun ni awọn ọmọ rẹ ti wọn n gbe South Africa, nipa ikọlu to n ṣẹlẹ si wọn, paapaa julọ lori iku awọn meji, Musa Yunana Joe ati Charles Iroegbu, lasiko iṣẹlẹ aburu naa," o fi kun ọrọ rẹ.

Ṣaaju, ijọba Naijiria ti sọ pe ohun to ku diẹ kaato ni lati maa ṣe ikọlu si awọn ọmọ ilẹ okeere ti wọn wa n gbe nilu wọn, ti wọn si n fiya jẹ wọn lọna aitọ, eyi ti ijọba nilo lati bojuto.

Ohun miran ti ijọba Naijiria n binu si nipa South Africa ni ti atẹjade ti wọn ṣafihan rẹ lori amohunmaworan nipa agbẹnusọ ilẹ South Africa, nibi to ti sọ pe ki awọn ọmọ Naijiria to n gbe lorileede wọn sọ ibi ti wọn fi awọn oogun oloro wọn pamọ si.

Ijọba Naijiria wa sọ pe "ọrọ to ku diẹ kaato ti wọn ko le tẹwọ gba ni wọn sọ, ati pe a bu ẹnu atẹ lu iru ọrọ bẹẹ."